Ará adúgbò rí egungun Onílé lẹ́yìn ọdún mérin tó ti kú

Aworan ile Aderemi John

Oríṣun àwòrán, others

Egungun gbigbẹ Ogbeni John Aderemi Abiola ni wọn ti ri ninu ile ologbe naa ni adugbo Adeosun/Idi Orogbo labẹ ijọba ibilẹ Ido ni ipinle Ọyọ.

Akitiyan awọn ara agbegbe naa pẹlu ifọwọsi awọn alaṣẹ ọlọpaa lati wọ inu agbala ologbe John Aderemi lati lọ ge igbo to wa ninu ọgba rẹ ̀ eyi ti o hu bo inu ọgba ati awọn ile to wa layika rẹ lo si aso loju ọrọ yii.

Yatọ sii igbo to ti kun bo gbogbo ọgba inu ile naa, ọkọ ayokele Volkswagen Golf alawọ funfun tun wa ninu ile naa.

Bi ọdun 2019 ṣe wọ inu ọdun 2020, ni awọn olugbe agbegbe Adeosun ti n gbiyanju lati se iwadi irinajo ọkunrin naa.

Meji ninu awọn ti oun ati won jo maa n sọrọ ni pe awọn ro wi pe ogbeni John Aderemi ti pada lọ si Port Harcourt, nipinle Rivers nibiti o ti n ṣe iṣẹ gẹgẹ bi onimo ẹrọ ni.

Leyin ti won ko ri i fun ayeye ọdun ileya 2018 wọn ro wi pe o ti pada duro ti idile rẹ ni ipinlẹ Rivers ni.

 Ipinnu awọn ara adugbo Adeosun ni ọdun 2022 lati san igbo to ti kun bo ile naa waye lẹyin ti ọgbeni Abiola ti ile re fegbekegbe pẹlu ti oloogbe Aderemi fi aidunnu re han si bi ejo se man wọ inu ile rẹ lati agbala oloogbe Aderemi to si le ṣakoba fun ẹbi rẹ.

Aworan Oko Ayokele Ologbe

Oríṣun àwòrán, Others

Bawo ni wọn se wa ri oku oloogbe?

Lẹyin ti wọn ti gba iwẹ asẹ lati aago ọlọpaa, awọn alagbase lo koko ṣẹ akiyesi oko ayokele Volkswagen Golf ti ogbeni Aderemi pẹlu nomba AKD769 DC nigba ti wọn ti san igbo ti o ti kun bo ayika ile na.

Awọn aladugbo ṣe akiyesi pe ferese iyara ogbeni Aderemi to wa ni ṣiṣi, eyi ti o fa iyalẹnu.

Ọkan ninu awọn Aladugbo Ọgbeni Mohammed Ademola pinnu lati sayewo ohun to wa ninu yara naa.

O jẹ iyalẹnu fun un nigba ti o ri egungun lori ibusun ninu iyara Ọgbeni Aderemi.

Ẹru ba wọn, iroyin naa si yara tan kalẹ ̀.

Lesekese ni oga ọlọpaa to n dari agbegbe Apete, SP Grace Akinsehinwa ran awọn ọlọpaa sibi iṣẹlẹ naa fun iwadii.

aworan ile

Oríṣun àwòrán, bbc/igbo

Aworan DRIVERS LICENCE

Oríṣun àwòrán, BBC/IGBO

Ìwádìí Ọlọ́pàá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yíì.

Ninu Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi sita ni won ti sọ pe awọn, mọlẹbi oloogbe naa fidi rẹ mulẹ pe orukọ oloogbe naa ni Aderemi John Abiola ati pe ọdun 2018 ni wọn ti ri i gbẹyin.

Atẹjade lati odo Alukoro Ile-iṣẹ oloopa ipinle Ọyọ, Adewale Osifeso ni pe Ibaṣepọ ile iṣẹ ọlọpaa pelu awọn ara agbegbe ti iṣẹlẹ na ti sẹlẹ lo je ki awọn tete ri idahun si iṣẹlẹ to so mọ iku oloogbe Aderemi John Abiola..

Ile iṣẹ BBC gbiyanju lati ba ẹbi oloogbe naa sọrọ sugbọn wọn ko setan lati sọrọ ni asiko yii.