Queen Elizabeth II: Wo ǹkan míì tí àwọn eèyàn ń sọ̀ nípa ìgbé ayé Obabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nomsa Maseko
- Role, BBC News, Johannesburg
Iku Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi Elizabeth II mu idaro wa lati ọwọ tolori tẹlẹmu jakejado agbaye.
Pupọ awọn eeyan lawọn ilẹ to figba kan wa labẹ akoso ilẹ Gẹẹsi ṣe iranti igbe aye Ọbabinrin to ku yi tawọn mii si ṣalabapin aworan igbe aye rẹ nigba to ṣabẹwo silẹ wọn.
Ṣugbọn bakan naa kọ ni ọmọ ṣ'ori.
Lọdọ awọn eeyan kan, iku Ọbabinrin yii jẹ iranti inira ti awọn eeyan koju labẹ ijọba amunisin.
Ninu nkan ti wọn ranti ni bi wọn ṣe ṣeku pa awọn eeyan lọna aitọ, jiji ohun alumọọni ilẹ wọn ati awọn ohun iṣẹnbaye lawọn ilẹ Iwọ Oorun Afrika, goolu ati diamond ni South Afrika ati ijiya ohun owo ẹru to waye ni India.
- Òkú Ọbabìnrin Elizabeth balẹ̀ sí Edinburgh, wo ìgbésẹ̀ tó kàn....
- Wó bí gbogbo ètò ìsìnkú náà yóò ṣe lọ ní Ọjọ́ Aje, Ọjọ́ Iṣẹ́gun, Ọjọ́ru àti Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀...
- Àwòrán àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ṣe àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́rán
- Ìjọba Nàìjíríà bu ọlá fún Ọbabìnrin Elizabeth II, wọ́n yóò sọ àsía sílẹ̀ dé ìdajì
Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa lo ṣapejuwe Ọbabinrin gẹgẹ bi akinkanju eeyan ti gbogbo agbaye yoo maa ṣe iranti rẹ fun daadaa to ṣe.
Amọ ẹgbẹ alatako ilẹ yi kan naa ti a mọ si: Economic Freedom Fighters party (EFF) sọ pe awọn ko ni ba wọn kẹdun iku Ọbabinrin Elizabeth rara.
Won ni pe : ''Ni igba aye rẹ gẹgẹ bi Ọbabinrin, ko gba wi pe ilẹ Gẹẹsi ati mọlẹbi rẹ hu iwa aburu jakejado agbaye; koda, niṣe ni o n gberaga lori ipa ti wọn ko''
Bayii ni ẹgbẹ alatako to tobi ṣikẹta nilẹ naa ṣe wi ti wọn si tun fi kun un pe: ''Iku rẹ jẹ iranti asiko to buru jayi nile wa ati itan igbesi aye ilẹ Afrika''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Loju opo ayelujara awọn eeyan sọrọ lodi nipa iku Ọbabinrin yi.
Ninu awọn ọrọ to n fa awuyeuwye loju opo Twitter ni eleyi ti Ọjọgbọn Uju Anya, ọmọ Naijiria kan, to fi Amẹrika ṣe ibugbe kọ soju opo naa.
Twitter yọ ọrọ naa kuro tori pe wọn lo tako ofin ibaraẹnisọrọ wọn.
Ninu ọrọ mii to kọ, o ni ''Bi awọn eeyan ba fẹ ki n kaanu Ọbabinrin to ṣakoso ijọba ipaniyan to si ṣi mọlẹbi mi nipo pada ti a si n ba wahala naa finra doni, ala ti ko ni le ṣẹ ni.''
O ṣeeṣe ki ọrọ rẹ yi maa sọ nipa ogun abẹle Biafra ni Naijiia nibi ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ti ṣe atilẹyin fun ijọba Naijiria.
Igbesẹ yi mu ki ebi pa awọn eeyan agbegbe yi ti ijọba Naijiria si pada bori Biafra ninu ogun yi.
- Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?
- Queen Elizabeth II: Níbo àti ìgbà tí ètò ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth máa wáyé?
- Wọn kéde ọba Charles Kẹta bii Ọba - Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìkéde náà tó wáyé lórí afẹ́fẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́?
- Camilla di Olorì tuntun
- Bí ètò Ọba jíjẹ àtàwọn tó le jọba ṣe yípadà rèé
- Camilla di Olorì tuntun
Eeyan kan loju opo Twitter @ParrenEssential fesi pada lori ọrọ Ọjọgbọn Uju to si ni bayii kọ ni awa ọmọ Naijiria ṣe n huwa.
''Iwa yi ko ṣafihan aṣa ati orile-ede wa Naijiria''
Awọn eeyan miran sọ pe iru iwa yi ko boju mu pẹlu iwa awọn eeyan ilẹ Afrika.

Oríṣun àwòrán, AFP
Kini awon eeyan mii tun so?
Bẹẹ lawọn mii naa kọ ọrọ nipa 'Diamond Star of Africa' ti wọn ni ki ilẹ Gẹẹsi da pada fun Africa.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, South Africa ni wọn ti wa okuta olowo iyebiye yii to si wa lori ade ti Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi n de sori.
Ọpọ lo ni ''wọn jii gbe ni''
Bo ti lẹ jẹ wi pe ijọba Transvaal ra a ti wọn si fi ta idile ọlọba ilẹ Gẹẹsi lọrẹ ni.
Amọ, nkan tawọn eeyan n sọ loju opo ayelujara ni pe awọn eeyan orile-ede South Africa lo ni Diamond yii.
Eeyan kan @Qban_Linx sọ pe Diamond yii ti iye owo rẹ to $400m to lati san owo ẹkọ Fasiti akẹkọọ ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin ilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa la ri pe hashtag "Kohinoor" bẹrẹ si ni gbilẹ lẹyin iku Ọbabinrin Elizabeth.
Wọn fi hashtag yi sita lati fi sọrọ nipa diamọndi ti yoo wa lori ade ti iyawo ọba tuntun yii de sori.
Awọn eeyan kan sọ pe o yẹ ki Ọbabinrin lo ipo rẹ lati ri i pe wọn da oku awọn to jagun tako ijọba aminisin ilẹ Gẹẹsi pada si ilẹ abinibi wọn.
Awọn eeyan Kenya ati South Africa n sọ pe ki wọn da ori awọn akinkanju bii: Koitalel Samoei to lewaju ogun Nandi ni Kenya laye atijọ tako ijọba amunisin pada.
Bẹẹ ni wọn sọ pe ki wọn ṣe iranti awon eeyan Kenya to padanu ẹmi wọn lasiko ikọlu Mau Mau.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Gitu Wa Kahengeribin jẹ nigba to darapọ mọ awọn ajijangbara lọdun mọkanlelọgọrin seyin.
Awọn ọmọ ogun ilẹ Gẹẹsi fi si ahamọ nibi ti wọn ti fiya jẹe, ti wọn si kọ lati fun ni ounjẹ.
O ni ''wọn gba ilẹ mi, wọn gba ẹtọ mi''
O sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ''A kan n ṣe idaro Ọbabinrin nitori pe ẹlẹran aran ni.'' Ko dun mọ wa pe ki eeyan ku.''
Ni Kenya niṣe lawọn eeyan n bẹnu atẹ lu aarẹ Uhuru Kenyatta to ṣapejuwe Ọbabinrin gẹgẹ bi ''ẹni alawokọṣe to ni ifarajin fun awọn eeyan.''
Aarẹ Kenyatta tun kede idaro ọlọjọ mẹrin ni iranti Ọbabinrin Elizabeth.














