Kenya Gay Policy: Ilé ẹ̀kọ́ gbogbo ní orílẹ̀èdè Kenya kò ní gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ "Gay" àbí "Lesbian"

Ilé ẹ̀kọ́ gbogbo ni orílẹ̀-èdè Kenya kò ni gba awọn akẹ́kọ̀ọ́ "Gay" àbí "Lesbian"-Ìjọba

Oríṣun àwòrán, MOgaha

Minisita fun eto ẹkọ lorilede Kenyan George Magoha ti ni ko si aaye fun awọ akẹ́kọ̀ọ́ akọ-si akọ tàbí abo-sí abo láàyè mọ́ nile iwe ti awọn akẹkọọ n gbe.

O ni eyi ni lati dẹkun ki awọn ọmọ naa ma kọ awọn akẹkọọ to ku ni iru iwa bẹẹ.

O fi kun un pe kaka bẹẹ o san ki wọn wa lọ awọn ile ẹkọ olojoojumọ ti wọn yoo si ma apada si abẹ obi wọn.

Bakan naa ni awọn to ba ti wa ni ilé ẹkọ ti wọn gbe ni wọn yoo dari pada lọ si ile ẹkọ oojo gẹgẹ bi o se sọ.

Minisita naa rọ awọn olori ile iwe ki wọn mu ọrọ naa gẹgẹ bi eyi to kan gbogbo eniyan ju bi o ṣe kan awọn ẹka kan ninu awujọ lọ.

Ẹwẹ, awọn ajafẹtọ ti ni awọn yoo pe minista naa lẹjọ nile ẹjọ lori ọrọ ọhun, wipe iru aṣẹ bẹẹ n tabuku ẹtọ awọn ti ọrọ naa kan.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, OYSG

Ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo ni orilede Kenya ni ijiya ẹsẹ ẹwọn ọdun mẹrinlelogun, bi o tilẹ jẹ pe wọn pe iru ofin yii lẹjọ ni ọdun 2019 sugbọn ile ẹjọ yi danu.

Ọjọgbọn Magoha naa tun fi kun pe ki wọn sẹ ayẹwo oogun oloro fun gbogbo awọn akẹkọọ ti ile iwe ba ti wọle ninu ọdun tuntun, o ni eyi yoo mu adinku ba lilo oogun oloro ni ilokulo, eyi ti o ni o pọ jantirẹrẹ jakejado orilede Kenya.

Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò

Atẹjade yii waye lẹyin ti ọpọ lọpọ ole ẹkọ di titipa ni saa to kọja lẹyin ti awọn ilé iwe ba awọn ile ẹkọ jẹ

Ọrọ ti Minisita sọ yii ti n mu ki àwọn ara Kenyan sọrọ pe minisitan n dẹyẹ si awọn ni ilana ibalopọ wọ yatọ si ti awọn eniyan to ku.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi