Àwọn agbébọn ṣèkọlù sí Sẹ́nétọ̀, gbẹ̀mí ènìyàn 5

Sẹ́nétọ̀ Ifeanyi Ubah àti àwọn ọkọ̀ tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí

Oríṣun àwòrán, Ifeanyi Ubah/Facebook

Kò dín ní ènìyàn márùn-ún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí àwọn agbébọn ṣe ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ Sẹ́nétọ̀ Ifeanyi Ubah ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Ní agbègbè Nkwo Enugwu-Ukwu, ìjọba ìbílẹ̀ Njikoka ìpínlẹ̀ náà ni ìkọlù ọ̀hún ti wáyé.

Kamen Ogbonna tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Sẹ́nétọ̀ náà ló fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀ fún BBC.

Fídíò ìkọlù náà tó gba orí ayélujára ṣàfihàn ọkọ̀ mẹ́ta tí òkú àwọn ènìyàn wà nínú rẹ̀.

Ogbonna ní àwọn òṣìṣẹ́ àti ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ Sẹ́nétọ̀ náà ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lọ àmọ́ Sénẹ́tọ̀ ọ̀hún tó wà nínú ọkọ̀ tí ọta ìbọn kò le wọlé sí móríbọ́ nínú ìkọlù náà.

Ó ní ìgbà tí wọ́n dé agbègbè ọjà Enugwu-Ukwu ni àwọn agbébọn tí wọ́n ti ń dènà dè wọ́n ya bò wọ́n tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní da ìbọn bolẹ̀.

Ó fi kún un pé iwájú àti ẹ̀yin ni àwọn agbébọn ọ̀hún ti ń yìbọn àti pé àwọn mìíràn ń jáde láti inú ọjà náà pẹ̀lú.

Bákan ló tẹ̀síwájú pé awakọ̀ Ifeanyi Ubah gbìyànjú láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn náà àmọ́ ó ní ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ òun ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ogbonna ṣàlàyé pé ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn wípé àwọn agbébọn le gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Ifeanyi Ubah nítorí ọ̀rẹ́ ará ìlú ló jẹ́.

Ọkọ̀ tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí

Oríṣun àwòrán, Ifeanyi Uba/Facebook

“Ohun tó le ṣe okùnfà irú ìkọlù yìí kò yé wa rárá nítorí ọ̀rẹ́ gbogbo ènìyàn ni Ifeanyi Ubah àti pé a ò mọ̀ ohun tí èyí túmọ̀ sí.”

“A ma gba àwọn òṣìṣẹ́ ààbò láyè láti ṣe ìwádìí wọn kí a wo ohun tí wọn yóò ṣe àwárí.”

Bákan náà ló ní ọ̀nà tí Sẹ́nétọ̀ náà máa ń gbà ní gbogbo ìgbà ni ọ̀nà tí àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù síi ni ọ̀nà náà jẹ́.

Ogbanna fi kún un pé láti ìgbà tí Ifeanyi Ubah ti gúnlẹ̀ sí Anambra, ọ̀nà Awka ló máa ń gbà fún àwọn ìrìnàjò tó ń ṣe lásìkò yìí nítorí náà ó ṣeéṣe kí ẹni tó bá fẹ́ dọdẹ rẹ̀ le mọ ìrìn rẹ̀.

Kíni ọlọ́pàá sọ?

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra, DSP Tochukwu Ikenga ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Echeng Echeng ti ṣaájú ikọ̀ ọlọ́pàá lọ sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Ikenga ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọlù náà rú ènìyàn lójú, àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ti wà ní agbègbè náà láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan múlẹ̀.

Ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fìdí òótọ́ múlẹ̀.

Ọkọ̀ tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí

Oríṣun àwòrán, Ifeanyi Ubah/Facebook

Gómínà Charles Soludo bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ìkọlù sí Sẹ́nétọ̀ Ifeanyi Ubah, ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ olùdíje sípò gómínà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Young Peoples Party, YPP ní ìpínlẹ̀ Anambra ti ń fa kí àwọn ènìyàn máa sọ̀rọ̀.

Ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn ènìyàn ni wí pé tí ọkọ̀ rẹ̀ kò bá nì ààbò láti rọ́ ọta ìbọn dànù ńkọ́.

Gómìnà Charles Soludo ní ìjọba ní ìfárajìn láti ríi wí pé gbogbo àwọn ọ̀daràn ni àwọn lé jáde kúrò ní ìpínlẹ̀ náà.

Soludo ní ìgbà ìkẹyìn rèé tí àwọn agbébọn yóò ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ni olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá Peoples Democratic Party, Atiku Abubakar ní ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ni ìkọlù náà jẹ́.

Atiku nínú àtẹ̀jáde lórí ayélujára ní orílẹ̀ èdè yìí níló láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá ní kíákíá lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè yìí.