Àwọn ará Ogbere-Tioya ké gbàjarè síjọba lórí afárá àdúgbò náà tó wó lulẹ̀

Awọn ará àdúgbò Ogbere-Tioya ni ijọba ibilẹ Ọna Ara, ni ilu Ibadan ti fi ẹdun ọkan han lori inilara ti wọn n dojukọ lori afaara ti o wa ni agbegbe naa.
BBC Yorùbá ṣe abẹwò si àgbègbè naa lọjọru, a si ri bi ogun lọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ṣe n to láti gba ori afárá naa kọjá. Àwọn òdọ́ ti wọn o le dúró lórí ila n gba inu odo ti afárá naa gba kọjá lọ si ibi iṣẹ wọn.
Ọkan ninu awọn ara agbègbè naa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣàlàyé wí pé wàhálà ti wọn dojúkọ ni àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ kìí ṣe kékeré.

O sọ wi pe lati igba ti afara adugbo naa ti ja ni àwọn ti ijọba gbe iṣẹ ọna náà fun ṣe afara tooro ti awọn ẹlẹsẹ lè gba.
Ṣùgbọ́n ero àdúgbò náà pọju afara ti wọn ṣe lọ, eleyii lo n mu ki awon eniyan maa to ni gbogbo igba ki wọn to le kọja.
Ontaja kan ni agbegbe naa ṣàlàyé wí pé ojoojumọ ni awon ènìyàn n ni ipalara lori afara naa nitori awọn irin ti wọn to si leti ti ya.
O ṣe afikun wi pe àwọn miiran maa n daku ti wọn ba ti pẹ lori ila ati pe ero to wa ni ayika wọn tí poju.
O ni ti ojo ba rọ, a ti gun afara naa maa n buru gan fún awon ara agbegbe naa.
Awọn ará adugbo náà rọ ìjọba ki o ṣamojuto iṣẹ ọ̀nà náà, ki ara le tu ará ilu.
Ọkàn ninu òṣìṣẹ́ tí ó bá BBC Yorùbá sọrọ ṣàlàyé wípé àwọn ti fẹ parí afárá mìíràn ti awọn ènìyàn yoo maa lo.
“Eyi fẹ́ o sì gba ọpọlọpo ẹsẹ.”
Ó ní ki o to di ọjọbọ, afárá náà yoo tii ṣe gba, awon yoo si wo eleyii to n pa awon ènìyàn lára ka.















