Gbogbo ìlú dá páropáro bí Buhari ṣe ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Imo

Aare Muhammadu Buhari ati Gomina Hope Uzodimma

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ṣíṣe abẹwo Aarẹ Muhammadu Buhari sì ipinlẹ Imo lati ṣe ifilọlẹ awọn opopona jẹ ọjọ ti ẹgbẹ ajijangbara IPOB pasẹ konile-o-gbele ni Ipinlẹ naa nítorí ọjọ yii ni igbẹjọ Olori ẹgbẹ IPOB Nnamdi Kanu.

Niṣe pupọ lara awọn olugbe olu ilu ipinlẹ Imo, Owerri sa pamọ si ninu ile wọn nítorí asẹ ẹgbẹ adijagbara IPOB gbe lelẹ ni Ipinlẹ naa.

Iwadi ileeṣẹ BBC fihan pe awọn eniyan agbegbe naa kuna lati jade sita kí Aarẹ Muhammadu Buhari kaabọ si ipinlẹ Imo.

Igbakejì re ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe abẹwo si ipinlẹ Imo lati ṣe ifilọlẹ awọn opopona ti ijọba Hope Uzodimma ṣe.

Aworan awon agbegbe to da paro
Aworan awon agbegbe to da paro
Aworan awon agbegbe to da paro

Bákan naa lo jẹ igbakeji ti awọn olugbe ipinlẹ naa kuna lati jade wa Aarẹ Muhammadu Buhari nítorí idunkooko awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara IPOB.

Lara awọn isẹ akanse naa ni opopona onibeji Owerri sì Orlu, Owerri si Okigwe ati ọfisi tuntun fun awọn ile gbìmọ aṣofin ipinlẹ naa.

Aarẹ gbe osuba fun gomina Hope Uzodimma fun isẹ ribiribi to ṣe ni Ipinlẹ naa, to si ni oun setan lati fọwọsowọpọ pẹlu ìjọba ìpinlẹ lorilẹede Naijiria fun ilọsiwaju and Itẹsiwaju gbogbo àwọn ipinlẹ lorilẹed Naijiria.