Damilola Olofingboyegun: Gbenga Olofingboyegun kò sí aàbò mọ́, ìrànlọ́wọ́ ni à n fẹ́ lórí ikú Gbenga Olofingboyegun
Awọn agbenipa ni wọn tun ti ṣọṣẹ nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ni bi wọn ṣe ge ori ọkunrin kan, Gbenga Olofingboyegun, lọ ti wọn si la aya rẹ.
Olofingboyegun to jẹ adari ẹka iwadi ati iṣiro lajọ to n moju to iṣẹ awọn olukọ (TESCOM) nipinlẹ Ondo lawọn mọlẹbi rẹ kede pe wọn ko mọ bo ṣe rin l'Ọjọbọ, ọjọ kini oṣu kẹsan ọdun yi lẹyin to kuro nibi isẹ lai dagbere.
Damilola Olofingboyegun to je omo oloogbe ati Arabinrin Modupe Olofingboyegun to je aya oloogbe ba BBC soro lori iṣẹlẹ naa.
Wọn sọ nipa ami ara to fu wọn saaju iṣẹlẹ naa ati awọn nkan to n ṣẹlẹ bayii.
Bakan naa ni wọn n beere fun iwadii ati idajọ ododo pẹlu ijiya to tọ si a\won to ṣiṣẹ ibi yii.
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò kúrò ní Buckingham ló sí Westminster Hall pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ ogun
- https://www.bbc.com/yoruba/articles/cxeggl5j0ego
- Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?
- Ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ òfin bíi 100 ni yóò ṣojú ASUU nílé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ tó pè tako ìjọba àpapọ̀
- A fẹ́ ìjìyà fún àwọn agbébọn tó pa ọkọ mi, ọ̀gá àgbà TESCOM ní Akure- aya Olofingboyegun
- Ètò ìforúkọsílẹ INEC, olùdìbò 1.126m ni ìjákulẹ̀ dé bá
- Akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH tó dá ìwé ẹ̀rí padà rí ẹ̀bùn owó N500,000:00 gbà
Kini o kọkọ ṣẹlẹ?
Awọn agbenipa ni wọn tun ti ṣọṣẹ nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ni bi wọn ṣe ge ori ọkunrin kan, Gbenga Olofingboyegun, lọ ti wọn si la aya rẹ.
Olofingboyegun to jẹ adari ẹka iwadi ati iṣiro lajọ to n moju to iṣẹ awọn olukọ (TESCOM) nipinlẹ Ondo lawọn mọlẹbi rẹ kede pe wọn ko mọ bo ṣe rin l'Ọjọbọ, ọjọ kini oṣu kẹsan ọdun yi lẹyin to kuro nibi isẹ lai dagbere.
Igbagbọ awọn mọlẹbi rẹ tẹlẹ ni pe wọn jii gbe ni, ti wọn si n reti ipe wọn lati dunadura.