Oludare Alaba: Akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH tó dá ìwé ẹ̀rí padà rí ẹ̀bùn owó N500,000:00 gbà lọ́wọ́ Onilede Solomon

Akekoo LAUTECH gba ebun

Akẹkọọjade LAUTECH ti o da iwe ẹri pada nitori airi iṣẹ ṣe ti gba ẹbun owo N500,000.

Akẹkọọjade fasiti Ladoke Akintola, LAUTECH to n bẹ niluu Ogbomọṣọ, Oludare Alaba ti tẹwọgba sọwedowo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira bayii lati ọwọ igbimọ ẹgbẹ akẹkọọjade fasiti naa.

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipejọpọ naa, aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade LAUTECH l'agbaye, Arakunrin Onilẹde Solomon ṣe alaye lori erongba won.

O ni wi pe lori ẹrọ ayelujara ni awọn ti dede ri fọnran kan ti o gba ode kan, nibi ti Oludare ti n ke tantan ninu ọgba Fasiti naa.

To si n pariwo wi pe oun fẹ da iwe ẹri ti o gba pada nitori oun ko ri nnkan gidi kan fi ṣe. Bẹẹ sini o tun un bere fun gbogbo owo ti o san lasiko ti o n kẹkọọ.

Solomon tẹsiwaju wi pe ọpọlọpọ ọdọ ti o ti kẹkọọjade ni ko ri iṣẹ ṣe, ṣugbọn ọna ara ti Oludare gbe ipenija ti ẹ gba lo mu ọrọ rẹ di tọrọfọnkale.

Àkọlé fídíò, Oludare Alaba, akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH ṣàlàyé ìdí tó fi dá ìwé ẹ̀rí rẹ̀ padà sí Fásitì tó ti ṣetá

Lara awọn ti akẹkọọjade naa n sọ ni lemọlemọ ninu fọnran naa ni wi pe oun ni ẹbun ti o pọ. Awọn ẹbun yii si le di owo ti oun ba ri oluranlọwọ ti yoo pese irinṣẹ.

Eyii lo mu ki igbimọ ẹgbẹ akẹkọọjade LAUTECH l'agbaye fi orikori lati da owo naa fun un.

Lara awọn oun elo ti wọn toka si ẹrọ ayarabiaṣa, foonu ati awọn ohun elo mii ti yoo fi maa da awọn eeyan lara ya.

Akekoo LAUTECH gba ebun

Lẹyin ti Alaba tẹwọgba sọwedowo naa ni o fi ọrọ naa lede lori ikanni ibanidọrẹ Facebook.

O ni, "Mo fi asiko yii fi imoore han si apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade LAUTECH, labẹ akoso aarẹ ẹgbẹ naa, Họnọrebu Onilede Solomon ti ọpọ eeyan mọ si LIMO, fun ẹbun sọwedowo #500,000 ti wọn fun mi lonii."

"Ki Ọlọrun ọba tẹsiwaju lati maa wa pẹlu igbimọ ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ fun ifẹ ati atilẹyin wọn."

Aarẹ ẹgbẹ naa wa parọwa si ijọba apapọ lati wa ojutu si iṣoro airi iṣẹ ṣe awọn ọdọ lorilẹede Naijiria, gẹgẹ bi o ṣe n ke si awọn ọdọ naa lati wa nnkan ti wọn le maa fi pawọda ki iṣẹ ijọba to de.