Àlàyé rèé lórí ohun tó ń fa awuyewuye láàrin Tinubu àti Obi

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Fídíò kan gba ori ayelujara kan tó ṣàfihàn ibi tí Peter Obi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ti ń fa awuyewuye lórí ayélujára.
Peter Obi nínú fídíò náà wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ètò ìdìbò Ààrẹ Nàìjíríà tó ń bọ̀ lọ́nà.
BBC News Yorùbá kò fìdí ibi tí wọ́n ti ya fídíò náà bóyá ní Nàìjíríà ni tàbí ìlú òyìnbó.
Àmọ́ fídíò náà ti ń fa ìfaǹfà láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń sọ̀rọ̀ wí pé kò yẹ kí wọ́n máa gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ẹni tó ń wá ipò Ààrẹ.
Kí ni wọ́n ń sọ nínú fídíò náà?
Peter Obi nínú fídíò náà ń fi fóònù rẹ̀ han ènìyàn kan pé àwọn alátìlẹyìn Tinubu ń fi àtẹ̀jíṣẹ́ kan ránṣẹ́ sí ara wọn lórí fóònù pé kí àwọn Yorùbá má dìbò fún òun nítorí òun jẹ́ ẹ̀yà Igbo.
Ẹni tó gbé fóònù rẹ̀ fún ọ̀hún sì ka àtẹ̀jíṣẹ́ náà síta fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ láti gbọ́.
Ohun tó kà síta náà ni pé “Ẹ̀yin ọmọ Yorùbá ẹ la ojú yin-ín o, tí ẹ bá dìbò fún Peter Obi, ẹ ti fún àwọn ẹkùn South-South àti South-East láyé nìyẹn.”
“Àwọn Igbo kò ní wá sí ìpínlẹ̀ Èkó mọ́ láti wá dókoòwò dípò bẹ́ẹ̀ ìpínlẹ̀ Delta àti Rivers ni wọn yóò máa lọ.”
“Ó ṣeéṣe kí wọ́n yé kọ́ ilé sí ìpínlẹ̀ Èkó mọ́ tí yóò sì ṣe àkóbá fún àwọn Yorùbá púpọ̀.”
“Lẹ́yìn tí ẹni náà ka àtẹ̀jíṣẹ́ náà tán ni Peter Obi sọ wí pé “ẹni tí ẹ fẹ́ fi ṣe Ààrẹ nìyẹn”
“Wọn ò gbèrò láti mú orílẹ̀ èdè dára, ìṣòro tí orílẹ̀ èdè yìí ní nìyẹn.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ikọ̀ ìpolongo Bola Tinubu ti bu ẹnu àtẹ́ lu fídíò náà.
Agbẹnusọ ikọ̀ ìpolongo ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Festus Keyamo ní ohun tí Obi ń ṣeni wí pé ó ń wá kí àwọn ènìyàn máa káànú òun ló ṣe gbé fídíò náà jáde.
Keyamo ní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni Peter Obi fẹ́ dá sílẹ̀ ni òun àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ ṣe ń gbé fídíò náà kiri lórí ayélujára.
Ó ní ẹ̀rù Tinubu ti ń ba Peter Obi bí ìpolongo ètò ìdìbò ṣe ti ń bọ̀ lọ́nà.
Ó wá rọ àwọn ènìyàn láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn náà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Kìí ṣe Peter Obi ló ṣe fídíò náà
Ẹ̀wẹ̀, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kan, Tanko Yunusa ti ní Peter Obi kò le sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.
Yunusa ní bí ọmọ ìyá ni Obi ń rí gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń díje nítorí náà kò le sọ ohun tí yóò tàbùkù wọn.
Ó ní gbogbo ìpolongo tí Obi ń ṣe ń dá lórí ibi tí bàtà ti ń ta àwọn ọmọ Nàìjíríà lẹ́sẹ̀.
Ó fi kun pé àwọn ènìyàn ti ń wá ọ̀nà láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ẹ̀yà kọ́ olùdíje àwọn lọ́rùn àmọ́ bogbo ọ̀nà ni àwọn ń gbà láti yẹrí nídìí rẹ̀.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé ó dá òun lójú pé Obi kò le ṣe fídíò náà.
Kokoko lara Tinubu le, ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ̀rọ̀ sókè

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/facebook
Igbimọ ipolongo oludije sipo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti sọ pẹ aheso ọrọ ni wi pe Bola Tinubu ti yọwọ kuro ninu idije aarẹ ọdun 2023.
Wọ́n ni irọ pọnbele ni iroyin ẹlẹjẹ naa, kii ṣe ootọ.
Adari ẹka iroyin fun igbimọ ipolongo Bola Tinubu,Festus Keyamo, ninu ọrọ re, sọ wi pẹ aheso ọrọ naa jade lori ikanni ayelujara awọn alatilẹyin ti oludije ẹgbẹ Labour Party, Peter Obi.
Keyamo ṣalaye wi pe awọn ọrọ irọ ati ọrọ ti n tan kale loriṣiriṣi lori ayelujara pe Asiwaju Bola Tinubu ti yọwọ ninu idije naa nitori ilera ara rẹ.
O fi kun pe ko si ohunkohun to ṣe Tinubu àti pe awọn iroyin ofege naa kọ seyin awọn alatilẹyin Peter Obi.
Keyamo ni “Bola Tinubu wa ni ilera pipe to si tun lokun lati koju ipolongo eto idibo to n bọ lọna.
Wọ́n ni irọ pọnbele ni iroyin ẹlẹjẹ naa, kii ṣe ootọ.
O ni awọn alatako ẹgbẹ APC yoo gbọ ọrọ lẹnu Tinubu funra rẹ laipẹ.













