Oludare Alaba, akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH ṣàlàyé ìdí tó fi dá ìwé ẹ̀rí rẹ̀ padà sí Fásitì tó ti ṣetán

Àkọlé fídíò, Oludare Alaba, akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH ṣàlàyé ìdí tó fi dá ìwé ẹ̀rí rẹ̀ padà sí Fásitì tó ti ṣetá

Mo ti ta pọnmọ gbigbẹ ri síbẹ̀ ko si iyatọ.

Arakunrin Alaba Oludare ni fonran fidio kan nipa rẹ gba ori ayelujara kan laipe yii.

Ninu fonran fidio naa lo ti yari pe ki Fasiti Ladoke Akintola University of Technology wa gba iwe ẹri ti wọn fun oun pada ki wọn si da gbogbo owo ile ẹkọ ti oun san pada fun oun.

Leyin ti fidio yii jade ni awon eeyan ti n sọ orisiirisii nipa eto ọrọ aje Naijiria lasiko yii.

Eyi lo je ki BBC Yoruba wa Oludare Alaba kan ki a gbọ ti ẹnu rẹ.

Kini Alaba so?

Oludare Alaba salaye diẹ lara igbesẹ ọrọ aje ti oun ti gbe sẹyin bii pe ki o maa ta ẹran pọnmọ, ko maa ṣiṣe agbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ sugbon ko yori si rere.

O sọ pe 'Agricultural Extension and Rural Development' ni ẹkọ ti oun lọ kó ni Fasiti LAUTECH sugbon gbogbo rẹ su oun ni oun ṣe roo pin lasiko yii pe boya owo naa a to lati se nkan mii.