ASUU- Tírílíọ̀nù 1.1 lowó àdéhùn tó wà láàrin wa àti Buhari, kìí ṣe bílíọ́nù N208

Oríṣun àwòrán, BASHIR AHMAD
Ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti ni Naijiria ti bẹnu atẹ lu biliọnu méjídínláàdọ́fà Naira owo iranwọ ti ijọba Naijiria buwọlu fawọn ile ẹkọ giga lorileede naa.
Aarẹ ẹgbẹ naa ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC sọ pe arumọjẹ lasan ni owo yi jẹ ati pe kii ṣe owo tawọn beere ninu adehun pẹlu ijọba.
Ogunyemi ni triliọnu kan naira le diẹ lawọn ati ijọba ṣadehun pe o yẹ ki wọn fi mu idagbasoke ba awọn fasiti Naijiria laarin ọdun 2013 si 2018.
Loju opo Twitter ọkan lara awọn oluranlowo Aarẹ Buhari,Bashir Ahmad ni ikede ibuwọlu owo yi ti jẹyọ ti ọpọ eeyan si n sọ pe yoo tan iṣoro iyanṣelodi ASUUni Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Kete ti o fi ọrọ yi sita lawọn eeyan ti n kan sara si ijọba fun igbesẹ yi
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3
Owo yi,ta lo wa fun
Gẹgẹ bi alaye ti aarẹ ASUU Biodun Ogunyemi ṣe lalaye, o ni ọna orisirisi ni ijọba ma n gba na owo fun idagbasoke eto ẹkọ ni Naijiria.
O ni yatọ si owo igbadegba ti ijọba ma n fun awọn ile ẹkọ fasiti,ile ẹkọ gbogboniṣe ati ile ẹkọ awọn olukọni,ijọba ṣe adehun lẹyin iwadi lori ipenija to n dojukọ idagbasoke fasiti lati san owo to le ni triliọnu kan naira laarin dun mẹfa.
''Owo ti wọn san yi, TETFUND lo n ṣe akoso rẹ wọn yoo si pin fun fasiti awọn ile ẹkọ poly ati ile ẹkọ awọn olukọni.Nibo wa lo ti tan iṣoro idagbasoke ta fẹ ki wọn ṣe ni fasiti?''
Ogunyemi ni ninu adehun awọn pẹlu ijọba o yẹ ki wọn san ''200 biliọnu naira lọdun 2013,ninu 1.3 triliọnu tawọn ṣadehun ki wọn si san eleyi to ku ni ipele 220 bilọnu naira laarin ọdun 2014,2015,2016 2017 ati 2018.''
O tẹsiwaju pe lẹyin 200 biliọnu ti wọn san ni 2013 ati 20 biliọnu nipari 2018,ijọba ko ṣika adehun tawọn jijọ ṣe pọ.
O tẹnumọ pe ohun tawọn bere kọ ni ijọba ṣe ati pe ijọba yi jẹ 1.1 triliọnu to yẹ ki o san fun idagbasoke fasiti ni Naijiria.
Nibẹrẹ ọdun 2019 ijọba Naijiria san biliọnu mọ́kànlélọ́gọ́jọ naira fawọn ile ẹkọ giga lorileede naa gẹgẹ bi owo iranwọ fọdun 2018 eleyi ti TETFUND ṣe eto pinpin rẹ.
Ninu owo yi, awọn fasiti ijọba kọọkan gba N785,832,700,awọn ile ẹkọ gbogbo niṣe kọọkan gba N536,703,502 ti awọn ile ẹkọ olukọni si gba N510,084,900.