NANS: Ọ̀wọ́ngógó owó ilé ìwé ló jẹ́ kí àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ máa fi fásitì sílẹ̀

AKEREDOLU

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Amọ ijọba ipinlẹ Ondo ni irọ ni adari awọn akẹẹkọ n pa nitori owó ilé ìwé kò nira láti san.

Ajọ to n risi ọrọ eto ẹkọ lorilẹede Naijiria (NANS) ti ni ọpọlọpọ akẹẹkọ lo ti kuro ni awọn ile iwe fasiti to wa ni ipinlẹ Ondo nitori Ọwọngogo owo ile iwe awọn akẹẹkọ.

Adari Ajọ NAN, Danielson Akpan lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ ni ijọba ti ile iwe fasiti Adekunle Ajasin (AAUA) ati Osustech pa ni ilu Okitipupa nitori awọn akẹẹkọ fẹhọnu han lori bi wọn se fi owo kun owo ileewe wọn.

Akpan ni ẹgbẹrun mejilelọgbọn (32,000) naira ni wọn n san tẹlẹ, amọ bayii awọn akẹẹko n san laaarin ẹgbẹrun lọna aadọta (150,000) si ẹgbẹẹrun lọna igba (200,000) naira gẹgẹ bi owo ile iwe. eleyii mu ọpọlọpọ akẹẹkọ miiran ko kuro nile ẹkọ, ti awọn miiran si n san aabọ gẹgẹ bi owo ile iwe.

Àkọlé fídíò, 'Lórí iṣẹ́ ikàn yìí, a ti kọ́ ilé, ọmọ ti lọ ilé ìwé'

Amọ, kọmisọnna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ondo,Yemi Olowolabi lasiko to n fẹsi si ẹsun yii ni awọn oloselu ni oun lo awọn adari awọn akẹẹkọ, ati wi pe awọn akẹẹkọ n san owo ile iwe lasiko lai si isoro kankan.