Akẹ́kọ̀ọ́jáde LAUTECH dá ìwé ẹ̀rí padà, ó fẹ́ kíléẹ̀kọ́ dá gbogbo owó ẹ̀kọ́ tó san padà
Àdéhùn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ló wà láàrín àwa àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́, a kò ṣèlérí iṣẹ́ - LAUTECH

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn alaṣẹ fasiti LAUTECH ti sọrọ lori fidio kan to n milẹ titi lori ayelujara ninu eyi ti akẹkọọjade fasiti naa kan ti da iwe ẹri rẹ pada.
Ninu fidio naa ni a ti ri akẹkọọjade ọhun, Oludare Alaba, ti n ba awọn oṣiṣẹ fasiti naa sọrọ, to n si sọ pe oun fẹ da iwe ẹri oun pada.
Awijare rẹ to fi fẹ se bẹẹ ni pe iwe ẹri naa ko wulo fun oun, oun si fẹ gba gbogbo owo ti oun ti san gẹgẹ bii owo ile ẹkọ pada.
O ni “ Ẹ ba mi mu owo mi, mi o kawe mọ, iya n jẹ mi.”
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ alabo fasiti naa n sọ fun pe ko ni suuru, amọ o ni iya n jẹ oun, ẹni iya n jẹ, ki i si se suuru.
‘Iwe ẹri mi ko wulo, ẹ gba a, ẹ ba mi ko owo ikẹkọọ ti mo san’
Alaba ṣalaye pe oun ti gbiyanju lati ṣe ohun ti awọn ẹgbẹ oun n ṣe nile aye amọ pabo ni gbogbgo igbiyanju oun ja si.
Alaba ni nitori naa, ohun to ku fun oun lati ṣe ni lati da iwe ẹri naa pada fun fasiti LAUTECH nitori ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun.
O ni “Eredi ti mo ṣe da iwe ẹri naa pada ni pe mo kan gba a ni, ko wulo fun mi.
Awọn anfaani ti mo n ri ko ju ki n bu ọṣẹ si ori lọ, ki n si ṣe oogun owo amọ mi o le ṣe oogun owo nitori mo fẹ wulo fun ara mi ati orilẹ-ede mi.”
Alaba sọ pe oun gbagbọ pe ti wọn ba da owo ti oun san nile ẹkọ pada fun oun, owo naa yoo wulo lati gbe ẹbun oun larugẹ, ki oun si gbe nnkan rere ṣe.
LAUTECH fesi fun akẹkọọ to da iwe ẹri pada
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan sawọn alaṣẹ fasiti naa, alukoro ile ẹkọ ọhun, Olalekan Fadeyi ba wa sọrọ lori isẹlẹ naa.
Fadeyi sọ pe awọn kii ba akẹkọọ wa iṣẹ, beẹ si ni awọn ko ṣeleri iṣẹ fun akẹkọọ kankan.
Alukoro fun fasiti LAUTECH naa ṣalaye pe idunadura to wa laarin awọn atawọn akẹkọọ, ni ki wọn kọ awọn eeyan naa lẹkọọ.
Amọ o ni kii ṣe isẹ fasiti naa lati ba wọn wa iṣẹ lẹyin ti wọn ba kẹkọọjade.

Oríṣun àwòrán, SR
‘Akẹkọjade naa ko yọju sawọn alasẹ LAUTECH, ori ayelujara la ti ri fidio to se’
O ni “Gẹgẹ bii anu rẹ ṣe yẹ ko ṣe wa to, pe ọmọ lọ sile ẹkọ ko si ri iṣẹ, LAUTECH kii ṣe ibi ti wọn ti n pese iṣẹ fun eeyan.
A ko si tọwọ bọwe adehun pe a o fun akẹkọọ nisẹ to ba jade tan nile ẹkọ wa.”
“Eeyan melo ni a fẹ wa iṣẹ fun, ṣe LAUTECH lagbara lati wa iṣẹ fun ẹnikẹni ni?”
“Mi o tii ri ọmọ naa bayii o, bẹẹ naa ni ko yọju si ọga agba ile ẹkọ wa atawọn ti ọrọ kan.
Bi ẹ ṣe ri fidio rẹ naa ni awa naa ṣe ri.”
“Ni bayii, ko tii wa ba wa sọrọ, to ba wa sọdọ wa pe oun fẹ ri VC, a oo mọ igbesẹ ti a maa gbe lori ọrọ rẹ.
Irufẹ nnkan bayii ko ṣẹlẹ ri lati ọdun 1990 ti wọn ti da LAUTECH silẹ.”















