A kìí ṣe àtẹ̀mẹ́rẹ̀ 'torí a kò darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì yín– KWASU, UNIOSUN fèsì fún ASUU

Aworan fasiti Uniosun

Oríṣun àwòrán, Others

Fasiti ipinlẹ Kwara, KWASU ati fasiti ipinlẹ Osun, UNIOSUN ti fun alaga ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU lesi lori ọrọ to sọ wi pe awọn fasiti ipinlẹ ti ko lẹṣẹnlẹ ni ko darapọ mọ iyanṣẹlodi ẹgbẹ naa.

Adari ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Emanuel Osodeke lo sọ lori ẹrọ tẹlifiṣọn pe awọn fasiti ti ko darapọ mọ wọn lati ja fun ẹtọ awọn olukọ fasiti ati awọn akẹkọọ, ofurufẹtẹ ni wọn ti wọn ko si lẹṣẹnlẹ.

O ti le ni oṣu meje ti ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ti wa ni iyanṣelodi ti wọn si n bere lọwọ ijọba lati ṣe atunṣe ẹka eto ẹkọ fasiti to fi mọ apo iṣuna ti yoo ma san owo awọn olukọ.

Amọ awọn fasiti bi fasiti ipinlẹ Osun, Fasiti ipinlẹ Kwara ati fasiti ipinlẹ Eko ko darapọ mọ iyanṣelodi ọhun.

Ninu esi wọn awọn adari ile ẹkọ fasiti naa ni ko si ọrọ ninu gbolohun to jade lati ẹnu adari ẹgbẹ naa.

‘’Fasiti Kwara kii ṣe atẹmẹrẹ, a n gbe orilẹede Naijiria ninu eto ẹkọ’’

Adari eto iroyin ileẹkọ Fasiti ipinlẹ Kwara, Saedat ni gbolohun to jade lati ẹnu alaga ẹgbẹ ASUU naa pe awọn fasiti ipinlẹ ko lẹṣẹnilẹ ko bojumu rara.

O ni fasiti awọn jẹ fasiti akọkọ lorilẹede Naijiria ti yoo fikun eto ẹkọ wọn lati maa kọ awọn akẹkọọ nipa iṣẹ ọwọ.

Bakan naa lo ni ọrọ ọjọgbọn naa ko ba ipo rẹ mu, ti awọn si le pee ni idukokomọni.

Fasiti Kwara ni ko tọ si lẹnu lati maa bu ẹnu atẹ lu awọn fasiti to ku nitori wọn ko darapọ mọ iyanṣẹlodi

Wọn wa kesi Alaga ẹgbẹ ASUU naa lati tete ni kiakia da ọrọ naa pada, ki o si tọrọ idariji lọwọ ileẹkọ to bu ẹnu atẹ lu.

Ẹjọ nlọ lọwọ lori awa ati ASUU ni a ko ṣe darapọ mọ iyanṣelodi – Fasiti UNIOSUN

Ninu ọrọ tirẹ, Adari agba ileẹkọ fasiti ipinlẹ Osun, Ọjọgbọn Odunayo Adebooye ti sapejuwe Alaga ẹgbẹ ASUU gẹgẹ bi ẹni to ma n sọrọ lai ronu.

Adebooye ni ko tọ si ASUU lati bu ẹnu atẹ lu fasiti ipinlẹ Osun nitori wọn ko darapọ mọ iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ.

O ni ọpọlọpọ awọn olukọ wọn lo jẹ onimọ oye dokita ti wọn si le ni irinwo, ti wọn n ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.

Bakan naa lo fikun un pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU lo yọ awọn igbimọ wọn kuro ni ipo, ti iru rẹ si ṣẹlẹ naa ni fasiti ipinlẹ Eko, nitori naa awọn ki n ṣe ara wọn lọwọlọwọ.

O fikun un pe ẹjọ awọn ati ASUU ṣi wa ni ileẹjọ lati bi ọdun marun un ṣẹyin.