Ṣé lóòtọ́ ni ọwọ́ tẹ awakọ̀ òfúrufú ọmọ ilẹ̀ France tó ń ta ohun ìjà fáwọn jàndùkú ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Banguiwood Media
Lẹnu lọọlọ yii ni aworan ọkunrin alawọ funfun kan bẹrẹ si n gba ori ayelujara, eyii ti awọn kan sọ pe ọkunrin naa lo n pin ohun ija oloro fun awọ agbesumọmi ni Ariwa Naijiria.
Ileeṣẹ iroyin 9newsng sọ loju opo Twitter rẹ pe ọkunrin naa ni awakọ ofurufu ẹlikọpita to n fi ọkọ ofurufu naa pese ibọn fun awọn janduku ni ipinlẹ Niger.
Akọle naa iroyin naa ni “Iroyin yajoyajo: Wọn ti fi ṣikun ofin mu awakọ ofurufu to n pin ibọn fun awọn janduku ni ipinlẹ Niger.”

Oríṣun àwòrán, Banguiwood Media
“Juan Remy ni orukọ ọkunrin naa ti awọn eeyan fi panpe ofin mu ni ipinlẹ Niger lori ẹsun pe oun lo n pin ibọn fun awọn janduku.”
Iwadii BBC tu aṣiri aworan ọhun
Iwadii ileeṣẹ iroyin BBC ti fi han pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa, kii sii ṣe ipinlẹ Niger ni Naijiria ni wọn ti ya aworan ọkunrin ọhun.
Lootọ ni ọwọ tẹ ọkunrin naa lori ẹsun pe wọn ka ibọn mọ lọwọ lọna aitọ, amọ kii ṣe ni Naijiria.
Orukọ ọkunrin naa ni Juan Rémy Quignolot to jẹ ọmọ orilẹ-ede France ni lootọ.
Ileeṣẹ iroyin Banguiwood Media, ni France lo kọkọ lo aworan ọkunrin naa lọjọ kẹwaa, oṣu Karun un, ọdun 2021 lẹyin ti wọn fẹsun kan pe wọn ka oniruru ibọn mọ lọwọ.
Ẹka ileeṣẹ iroyin BBC to n tu aṣiri iroyin ẹlẹjẹ fidi rẹ mulẹ pe ko si ẹri kankan to fi han pe wọn mu afurasi naa ni Naijiria, tabi pe oun lo n ta ibọn fun awọn agbesumọmi nipinlẹ Niger.












