Germany yóò dá ère Naijiria 512 tí àwọn kan jí kó padà

Oríṣun àwòrán, AFP
Orilẹede Germany ti tọwọ bọ iwe adehun lati da ere ti wọn kọ ni ilu Benin lorilẹede Naijiria pada.
Ere ‘’bronze’’ ti iye rẹ jẹ mẹjila ati ẹẹdẹgbẹta(512) ni won jiko ni sẹnturi to kọja(19th century).
Adehun naa lo waye laarin ajọ Foundation of Prussian Cultural Heritage (SPK) ati Ajọ Nigeria's National Commission for Museums and Monuments (NCMM).
Ọkan lara ere naa ni wọn yoo da pada ni ọdun yii lati ilu Berlin, ni Germany nibi ti wọn n ko awọn ohun abalaye si.
Awọn ologun ikọ amunisin ni wọn ji awọn ere ko lọ ni Naijiria ti wọn si ta a
Amọ fun ọdun mẹwaa ni ọpọlọpọ awọn ere naa yoo fi wa ni Berlin gẹgẹ bi ohun ti wọn ya, nibi ti wọn yoo patẹ rẹ si fun awọn eniyan lati maa wo o.
Awọn ere idẹ yii ni wọn rọ lati ilu Benin nipinlẹ Edo, amọ ti awọn ikọ ologun awọn amunisin jigba laye ọjọ ọhun.
Eyi mu ki ọpọlọpọ ninu awọn ohun manigbagbe yii wa ni ilẹ Yuroopu ti wọn si n ta fun awọn oniṣowo ati awọn onibara.
Ni Osu Kẹrin, ọdun 2021 ni ijọba ilẹ Germany pinnu lati da awọn ere ide yii pada fun orilẹede Naijiria.












