Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ ṣọ́ra fún Northern Cyprus – Ìjọba àpapọ̀

Abike Dabiri-Erewa

Oríṣun àwòrán, @nidcom_gov

Ijọba apapọ ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣora fun lilọ si orilẹ-ede Northern Cyprus.

Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, NiDCOM, Abike Dabiri-Erewa, lo kilọ bẹẹ.

Ikilọ yii lo n waye latari bi wọn ṣe n pa awọn ọmọ Naijria ni ipakupa nilẹ naa.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, Dabiri-Erewa sọ pe ko fi bẹẹ si nnkankan ti ijọba Naijiria le ṣe si ohun to n ṣẹlẹ ni Northern Cyprus, nitori ko si orilẹ-ede kankan lagbaye to da ilẹ naa mọ gẹgẹ bii orilẹ-de ayafi Turkey nikan.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere lati maṣẹ bẹru ati pada wale lati da ileeṣẹ silẹ nitori eto abo to mẹhẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Dabiri-Erewa gba pe lootọ ni nnkan ko ṣẹnu ire nipa ti eto abo Najiiria, o ni nnkan ko ni maa ri bo ṣe wa yii lọ nitori ijọba apapọ n sa gbogbo ipa ipa rẹ lati yanju iṣoro naa.

O pari ọrọ rẹ pe nnkan bii ogun biliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika ni awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun fi ranṣẹ sile lọdun 2021 nikan ṣoṣo.