Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun Naijiria ń pa àwọn àgbẹ̀ nínú oko wọn nílẹ̀ Ibo?

Fake news

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni kan fọto bẹrẹ si n milẹ titi loori ayelujara, ninu eyii ti awọn eeyan ti fẹsun kan awọn ọmọ ogun Naijiria pe wọn n fiya jẹ awọn agbẹ kan lai nidi.

Aworan naa ni ẹni to kọkọ fi lede lori ayelujara kọ akọle kan si pe ipinlẹ Abia ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Akẹle ọhun ni “Bayii ni awọn ọmọ ogun Naijiria ṣe n dukoko, ti wọn si n pa awọn baba wa ti wọn lọ ṣiṣẹ ninu oko... ipinlẹ Abia ni iṣẹlẹ yii ti waye lonii ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022.”

Amọ ṣe lootọ ni awọn ṣọja n pa awọn baba agbalagba to jẹ agbẹ ninu oko wọn nipinlẹ Abia?

BBC tu aṣiri aworan naa

Iwadii ti ẹka to n gbogun ti iroyin ẹlẹjẹ nileeṣẹ iroyin BBC ṣe fi han pe irọ ni ọrọ naa ti awọn eeyan n pin kiri nipa aworan ọhun.

Tako iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara, orilẹ-ede Cameroon ni wọn ti ya aworan naa.

Ọmọ ogun orilẹ-ede Camerron lawọn ologun to wa ninu aworan naa lati ẹka Rapid Intervention Battalion.

Ni ṣe ni awọn ologun naa lọ doola awọn araalu to wa ninu aworan ọhun tako ohun ti awọn eeyan n sọ ni Naijiria pe ṣe ni wọn lọ fi panpẹ ofin mu wọn.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 si ni wọn ya aworan naa tako akọle to wa lara rẹ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 ni iṣẹlẹ naa waye.

Ẹwẹ, kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan ni Naijiria tabi Cameroon yoo lo awọran lati orilẹ-ede miran fun iroyin ẹlẹjẹ.