Ọwọ́ agbófinró tẹ Olùkọ́ tó jí aṣọ ọlọ́pàá kó ní Abeokuta ṣùgbọ́n tó ń díbọ́n bíi ọlọ́pàá ní Ibadan
Kele ofin gbe ayederu ọlọpaa n'Ibadan
Afurasi ẹni aadọta ọdun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adebisi Ayodele ni kele ofin ti gbe bayii.
Lọjọ Aiku ni ọwọ tẹẹ ni agbegbe Aṣejire n'ijọba ibilẹ Ẹgbẹda niluu Ibadan nibi ti o ti mura ti o si n ṣiṣẹ ọlọpaa lọna aitọ.
Nọmba ọkọ Mitsubishi kan ti o fi n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹṣọ aabo ni: ARP 34 AA.

Oríṣun àwòrán, @NPF
Lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ n fi oju awọn ọdaran kan han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyele nilu Ibadan ni ọrọ jade.
Kọmisọnna Ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ, Adebowale Williams ṣe alaye fun awọn akọroyin pe oṣiṣẹ ijọba to n bẹ ni ipele ikẹrinla ni Adebisi Ayodele, ti o si n ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Ikereku-Idan, ilu Abẹokuta n'ipinlẹ Ogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa fi idi ọrọ mulẹ wi pe Ayọdele ti fi oju han gẹgẹ bi ọṣiṣẹ ọlọpaa fun ọpọlọpọ ọdun ki ọwọ palaba rẹ to ṣegi.
Ninu ọrọ tiẹ, afurasi naa jẹwọ wi pe niṣẹ oun ji aṣọ ọlọpaa ati awọn eroja mii ti oun lo ọdọ aladugbo kan niluu Abẹokuta.
O ni, "Mo ji aṣọ ati awọn eroja ti o ku niluu Abẹokuta. Olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mi, mo si wa ni ipele ikẹrinla lẹnu iṣẹ ijọba.
Bẹẹ sini mo fẹran iṣẹ ọlọpaa gan an de ibi wi pe gbogbo awọn ara adugbo wa ni mo ti sọ fun wi pe ọlọpaa ni mi."
Ayọdele fi kun ọrọ rẹ wi pe ni ọdun marun sẹyin ni oun ji aṣọ naa ko ti oun si ti n fi ṣiṣẹ, ṣugbọn oun ko fi aṣọ naa hu iwa ọdaran ri.
Ọlọ́pàá tó bá gbá fóònù yin láti yẹ̀wò. ọdaràn ni – Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Nurudeen Adebule
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kilọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ lati dẹkun ati maa yẹ foonu awọn araalu wo loju popo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Muyowa Adejobi lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ irtoyin abẹle Channels.
O ni “Ẹ dẹkun a ti maa yẹ foonu awọn eeyan wo, ẹ ko lẹtọ lati maa wo foonu awọn eeyan, ohun ini ẹni naa ni, ẹ ko si lẹtọ lati yẹ wo.”
Ọlọ́pàá tó bá gbá ojú aráàlú, ọdaràn ni – Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Adejọbi sọ pe iwa yiyẹ foonu wo lọna aitọ yii jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹsun ti awọn araalu fi n kan awọn ọlọpaa.
A n sa ipa wa lati fọ ileeṣẹ ọlọpaa mọ
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni ileesẹ ọhun n ṣe gbogbo ohun to le ṣe lati ri pe wọn yọ awọn kọlọrọsi to n ba orukọ ileeṣẹ naa jẹ danu.
O ni “Lẹnu iṣẹ ọlọpaa, a ni awọn alaigbọran, ko si ọlọpaa ti ko mọ pe ohun gbọdọ wọ aṣọ iṣẹ oun daadaa, ko gbọdọ mu siga lẹnu iṣẹ, ko gbọdọ gba oju araalu, ko si gbọdọ fi ada na araalu.”
“Ko si ọlọpaa kankan ni Naijiria lonii ti yoo sọ fun mi pe oun ko mọ awọn nnkan wọnyii nitori ara awọn nnka ti an kọ wọn nile ẹkọ ọlọpaa niyẹn.”
Ileeṣẹ ọlọpaa yoo tẹsiwaju lati maa ba awọn alaigbọran wi
Adejobi sọ pe gbogbo iṣe ileeṣẹ naa lo wa in ibamu pẹlu ofin, awọn yoo si tẹsiwaju lati maa fi iya to tọ jẹ eyikeyi ọlọpaa to ba tapa si ofin.
O ni “Gbogbo ẹṣẹ ti ọlọpaa ba ṣe lo ni ijiya labẹ ofin, to ba jẹ ki a rẹ ipo irufẹ ọlọpaa bẹẹ silẹ ni, a oo ṣe bẹẹ, to ba si jẹ ki a gba iṣẹ lọwọ irufẹ ẹni bẹẹ, a oo ṣe bẹẹ pẹlu.”
“Bawo ni ọlọpaa ṣe le maa duro laarin ọna lati maa gba owo lọwọ awọn eeyan? Iwa ọdaran ni!”
“Gẹgẹ bii ọlọpaa, ti o ba na araalu, o ti wu iwa ọdaran.”












