Àwọn jàndùkú da ìfinijoyè Baálẹ̀, Mógàjí rú ní Ibadan, Olubadan faraya!

Aworan

Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Lekan Balogun ti da ifinijoye awọn baalẹ ati Mogaji duro lasiko yii lẹyin ti awọn janduku da ifinijoye baalẹ ati Mogaji ru ni ilu Ibadan.

Lasiko ti BBC n ba agbẹnusọ olubadan sọrọ lo salaye bi iṣẹlẹ ṣẹ waye.

O awọn alatilẹyin awọn ti wọn lero pe wọn yo fi awọn joye nibẹ lo bẹrẹ si ni da ibẹ ru.

Ti wọn n pariwo, ti wọn ko si fun awọn eniyan laaye lati ṣe ifinijoye naa ni irọwọrọṣẹ.

Lẹyin naa ni wọn fi opin si ifinijoye naa, ti o si jẹ pe eniyan mẹta ninu mẹwaa nikan ni wọn fi jẹ oye ni ana.

Agbẹnusọ naa ni awọn ọmọ ganfẹ to ba da ibẹ ru jẹ awọn alatilẹyin awọn ti wọn fẹ jẹ oyẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe wọn ko lọ aṣọ mọ ẹnikẹni lọrun,amọ niṣe ni wọn n pariwọ di gbogbo ohun ti wọn n ṣe lọwọ

Ohun ti o ṣẹlẹ buru jai , o ti ni loju – Olubadan

Olubadan ti ilu Ibadan, Oba Lekan Balogun ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ bi awọn janduku ṣe da ifinijoye ru ni aafin.

Ọba ni ohun to ṣẹlẹ naa buru jai to si tini ni oju nitori awọn eniyan naa ko bu ọla fun ori ade to wa ni ori ijoko to fi mọ awọn oloye nla nla ni ilu Ibadan.

O ni awọn yoo ri pe iru iṣẹlẹ yii ko waye mọ, ti ijiroro si n lọ lọwọ lori bi wọn yoo ṣe maa ṣe lati isinyii lọ lai si rukeruke.

Olubadan

Oríṣun àwòrán, @Olubadan

Olubadan ni o ṣeeṣe ki wọn gbe ifinijoye naa kuro ni aafin abi ki wọn ṣe afikun awọn agbofinro ti yoo ma wa nibẹ, ki iru iwa ibajẹ naa ma tun waye mọ.

Bakan naa ni o fikun un pe awọn meje to ku ki wọn jẹ oyẹ ni wọn yoo kọkọ da lohun ti wọn ba ti bẹrẹ ifinijoye pata.

O ni ko si wahala ninu rẹ amọ ki wọn kọkọ lọ tun ile wọn sẹ naa ki iru iṣẹlẹ to waye naa ma tun waye mọ.