Wo àwọn olóṣèlú tí àwọn ọmọ Naijiria ti fi aṣọ wọn ṣe yẹ̀yẹ́ rèé...

Oríṣun àwòrán, Google
Oju opo Twitter gbona janyinjanyin lasiko ipade ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria nitori aṣọ ti oludije fun ipo igbakeji aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC, Kashim Shettima wọ lọ si ibi ipade naa.
Lara awọn to sọrọ loju opo Twitter ni gbariyẹ ni ''suit'' to wọ, ti ''tie'' ọrun rẹ si gun ju bo ṣe yẹ lọ.
Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu bata ẹṣẹ rẹ, iyẹn ''Sneakers'' to wọ lori ''suit''.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Amọ awọn ẹlọmiran ni ko si ohun to buru nibẹ nitori aye ti n yi pada, ti awọn eniyan si n wọ suit pẹlu sneakers papọ lọ si ibi aṣeyẹ tabi ipade.
Àwọn olóṣèlú tí àwọn ọmọ Naijiria ti fi aṣọ wọn ṣe yẹ̀yẹ́ rẹ...
Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Google
Ọdun 2021 ti aarẹ Buhari ṣe abẹwo si Oweri nibi ti o ti lọ si iṣẹ akanṣe mẹrin, ti gomina Hope Uzodinma se ni asiko iṣejọba rẹ.
Aarẹ Buhari to wọ aṣọ ibilẹ awọn ẹya Igbo (Isi-agu pẹlu sọkoto rẹ) ni wọn fi ṣe yẹyẹ pe ko duro daradara ni ara rẹ.
Ọkan lara awọn to bu ẹnu atẹ lu aṣọ naa nigba naa ni Reno Omokri to n bẹrẹ idi ti aarẹ fi wọ aṣọ naa, ati pe ẹni to ran aṣọ naa ko fẹran aarẹ Buhari rara.
Patience Jonathan

Oríṣun àwòrán, Google
Iyawo aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Patience Jonathan di ilumọọka lori ẹrọ ayelujara ni ọdun 2017 nitori aṣọ to wọ to ni iyẹ.
Awọn eniyan wa fi aworan aṣọ naa ati aworan adiye papọ pẹlu akọle pe aṣọ naa jọ iyẹ adiyẹ
Salamatu Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Google
Iyawo abẹnugan ile aṣofin agba ni Naijiria, Salamatu Gbajabiamila ni aṣọ rẹ tu ori ayelujara ka nitori aṣọ rẹ to wọ jade.
Bi o tilẹ jẹpe aṣọ designer lo wọ, arabinrin naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu pe oriṣiriṣi awọ lo ko kọ ara to fi mọ bata ẹṣẹ rẹ.
Asọ to wọ naa ati bata rẹ pẹlu aago ọwọ ni wọn ni o le ni miliọnu mejila naira, amọ ti ko wuyi loju nitori bi o ṣe too pọ.
Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Google
Aworan minisita fun iroyin ati asa lorilẹede Naijiria, Lai Mohammed lo jade nibi ti o ti wọ aṣọ ibilẹ Naijiria, to si wọ suit si lori ni paapaa iṣere ni orilẹede Spain.
Ẹni to gbe aworan naa jade ni ki ni suit ati agbada niiṣe papọ pẹlu fila?
Minisita naa lo duro pẹlu awọn miran lati ya fọtọ pẹlu suit jacket to gbe lori agbada naa.
Ohun tí Atiku, Peter Obi , Tinubu sọ pé àwọn yóò ṣe fún Naijiria nìyíí...

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti tẹle ọrọ ti awọn oludije sipo aarẹ lorilẹede Naijiria sọ pe awọn yoo ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ti awọn ba di aarẹ.
Awọn oludije sọ ọrọ yii lasiko ipade ọdọọdun ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorilẹede Naijiria (NBA Conference).
Peter Obi ati Atiku Abubakar lo gun ori apele lati ba awọn eniyan sọrọ ni ilu Eko, nigba ti Kashim Shettima ṣoju fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Atiku Abubakar
Ninu ọrọ rẹ, oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ni ọr eto ẹkọ lorilẹede Naijiria jẹ oun logun, paapaa iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU gunle to ti fa ifaṣẹyin fun eto ẹkọ awọn akẹkọọ ni Naijiria.
Atiku ni ohun ti oun yoo ṣe ni lati sọ gbogbo fasiti ijọba apapọ di fasiti ipinlẹ, ki wọn le maa ṣakoso rẹ.
O ni ijọba apapọ ko ni ohun ini to kunjuwọn lati sakoso awọn fasiti ni Naijiria.
O ni awọn fasiti ohun yoo wa ni ipo to yẹ, ti yoo si faaye silẹ fun awọn akẹkọọ lati oke okun lati wa kọ ẹkọ ni Naijiria.
Bola Tinubu
Igbakeji oludije aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Kashim Shettima lo ṣoju fun Bola Ahmed Tinubu.
Gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ naa ni awọn ni ọna abayọ si eto ọrọ aje Naijiria to dẹnukọlẹ lọwọ.
O ni awọn yoo fi apẹrẹ aṣeyọri ti wọn ṣe ni ipinlẹ Eko ati Borno to fi mọ awọn ipinlẹ miran lati mu ayipada ba orilẹede Naijiria.
Shettima ni ohun kan pato ti orilẹede Naijiria kuna lọwọlọwọ ni adari to kunjuwọn, ti wọn si ni ki awọn ọmọ Naijiria ma dibo fun awọn oloṣelu to lẹnu ni ọdun 2023.
Peter Obi
Oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ni ọrọ aje to dẹnukọlẹ ni Naijiria nilo amojuba ni kiakia
Obi ni ọna abayọ ni lati pe awọn oludokowo si ẹka eto ẹkọ, eto aabo ati ọrọ ina lati mu idagbasoke ba ọrọ aje ni Naijiria.
O ni agbegbe ti eto aabo ba muna doko, ti awọn eniyan tẹle ofin ati ilana, aridaju wa pe awọn oludokowo yoo wa sibẹ lati jiroro lori ọrọ aje.
Ohun ti awọn eniyan sọ nipa awọn oludije sipo aarẹ ni Naijiria niyii
Ero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọtọ lori awọn oludije wọn.
Lara awọn to fi ero wọn lori ọrọ ti awọn oludije sọ ni ko bojumu bo ṣe jẹ pe Shettima lo ṣoju Tinubu ati wi pe nibo ni oludije sipo aarẹ naa wa.
Bakan naa ni wọn tun ṣe ẹfẹ lori aṣọ ti Shettima wọ to fi mọ bata rẹ.
Lara awọn to wa nibi ipade awọn agbejọrọ naa ni oludije sipo aarẹ, Kingsley Moghalu, Onkọwe Chimasmanda Adichie ati awọn eniyan jankanjankan miran.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

Oríṣun àwòrán, @Twitter












