Ohun tí àwọn èèyàn ń sọ rèé lẹ́yìn tí adari àwọn agbésùnmọ́mí Zamfara, Bello Turji ní òun ti ronúpìwàdà

Oríṣun àwòrán, @bulamabukarti
Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Zamfara ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa sọ pe gbajumọ ọmọ ẹgbẹ agbseumọmi ni, Belllo Turji, ti ronupiwada.
Igbakeji gomina ipinlẹ naa, Hassan Nasiha lo fi ikede naa sita pe ọkunrin ọhun, ti ọpọ mọ si ‘Sarkin Yan Ta’adda’ to n tumọ si ọba awọn janduku, ti ronupiwada.
Fun ọpọlọ ọdun ni ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe awọn n wa ọkunrin naa fun oniruru ẹsun janduku ati igbesumọmi ni Zamfara to jẹ ipinlẹ rẹ, atawọn ipinlẹ mii to wa layika bii Sokoto ati Katsina.
Ọkan lara awọn ti awọn agbesumọmi ti ṣe ipalara fun awọn eeyan rẹ, Hafizu Bala sọ pe o dara bi Turji ṣe ronupiwada o, amọ kii ṣe igba akọkọ ree ti janduku yoo sọ pe oun ti yipada ṣugbọn ti yoo tun pada sinu eebi rẹ.
O ni “Ọkunrin yii atawọn ẹmẹwa rẹ ti ṣọṣẹ ti ko ṣe fẹsnusọ nipinlẹ wa, ohun to dara ni pe o ti ronupiwada.”
“Ṣugbọn sibẹsibẹ naa ominu n kọ mi, nitori a ti ri awọn agbesumnọmi kan bii Auwalu Daudawa to sọ pe oun ti yipada amọ to pada sinu iwa rẹ atijọ.”
Ẹlomiran to tun sọrọ, Jamiu Umaru ni ohun ayọ ni pe Turji yipada ṣugbọn oun ko le gbagbe iru itu ti ọkunrin naa ti pa ṣeyin pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ.
Ẹwẹ, ọpọ eeyan kaakiri iha Ariwa lo ni inu awọn dun pe Turji yipada nitori yoo da alaafia pada si agbegbe awọn.
Awọn eeyan kan tilẹ woye pe ọkunrin ọhun yoo wulo lati yi ọkan awọn ẹmẹwa rẹ to ṣi n ṣiṣẹ agbsumọmi pada ni bayii ti oun funra rẹ ti n gbe igbe aye tuntun.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Bello Turji ree
Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe Turji lo wa nidi oniruru iwa janduku ati igbesumọmi to n ṣelẹ ni iha Ariwa.
Wọn bi ni ijọba ibilẹ Shinkafi, nipinlẹ Zamfara.
Olukọ fasiti imọ itan ni fasiti Danfodio, Murtala Ahmad Rufai ni ọjọ ori ọkunrin naa ko tii le ju ọdun mẹtadinlọgbọn si marundinlogoji lọ.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ, o kẹkọọ daadaa nipa ẹsin Musulumi.
Iṣẹ to kọkọ yan laayo ni ko maa ji maalu oni maalu gbe, ko to rekọja si iṣẹ igbesumọmi lẹkunrẹrẹ.












