Osun election tribunal: PDP ti fèsì sí ẹ̀bẹ̀ ẹsùn ẹjọ́ tí Gómìnà Gboyega Oyetọla pè lórí èsì ìdìbò gómìnà Osun

Adeleke, Oyetola

Oríṣun àwòrán, Others

PDP dahun si ẹsun Oyetọla ati APC, O ni pe ki ile ẹjọ da ẹjọ naa nu.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ awọn agbẹjọro gomina Oyetoal ti APC ni Osun.

Gomina Oyetola to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati ẹgbẹ rẹ APC lo tako esi idibo gomina to waye ni oṣu Keje, ọjọ kerindinlogun, ọdún 2022 niwaju ile-ẹjọ.

Gomina Oyetọla ati ẹgbẹ APC sọ pe awon ibo ti won di ni àwọn ijọba ibilẹ kan ju ohun ti o yẹ lọ ni ipinlẹ naa ninu eto ibo gomina to kọja.

Kini o wa ṣẹlẹ bayii?

Alaga igbimọ alabojuto PDP l'Osun Dokita Adekunle Akindele ninu esi rẹ ro ile-ẹjọ Idibo lati fagile ẹbẹ Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu APC, ti o sì ṣapejuwe rẹ pe ko ja si nkankan nitori pe isọ ni, ati pe ko si ipilẹ ti o fi le duro nitori pe fifi akoko sofo lasan ni yoo jasi.

Àkọlé fídíò, A ti kọ lẹ́tà sí ìjọba pé à ń ló kúrò ní Nàìjíríà, gbèndéké àsìkò ní à n dúrò dé

Adekunle wa salaye siwaju pe Seneto Ademola Adeleke lo ye ki won kede gege bi ẹni tó jáwé olubori bi o ti yẹ.

O si so wi pe ko si ibi ti ibo ti ju ohun ti o yẹ kí wọn kéde lọ ni gbogbo awon ibudo idibo ti gomina Oyetola ati ẹgbẹ APC gbe wa siwaju ilé ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

Kini nakn mii ti Adekunle tun sọ?

Akindele Adekunle tun jẹ ko di mimo pe ètò idibo naa jẹ eyiti o lọ ni alaafia, pẹlu ootọ ati igbẹkẹle laisi eyikeyi ti o ta ko ibamu pẹlu Ofin Idibo, ọdun 2022.

PDP tun je ko di mimọ pe awọn ẹsun ati ẹbẹ ti gomina Oyetola gbe lo ile ẹjọ jẹ Iro nla ti ko le fidimule ati èrò tí kò lè wa sí imusẹ.

Àkọlé fídíò, Udeh Meshack Otobo ni ọmọ Benue to n dín àkàrà tà ní Ofa, Ososgbo, Ilorin àti Ife fi n paw

Akindele pari ọrọ rẹ pe ipejo awuyewuye ètò ìdìbò ti gomina Oyetọla ati ẹgbẹ rẹ APC gbe wa sí ilé ẹjọ wa fún lati fi akoko sofo ati igbiyanju ni asan.

O fi kun un pe Seneto Ademola Adeleke ti o jẹ oludije fun ẹgbẹ òṣèlú PDP ati gomina ti gbogbo eniyan ipinle Ọsun yan ni o kunju osunwon lati dije fun eto idibo naa.

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́

Imoran wo ni PDP wa gba APC ni Osun?

Nitori naa ẹgbẹ oṣelu PDP wa gba ẹgbẹ oṣelu APC ati Oyetola lamoran pe ki won gba ijakule wọn t'owaye ninu ètò ìdìbò tokoja.

O ni pe ki won dekun ijakule egan, ki won si bere ilana lati gbe isejoba kalẹ fún Seneto Ademola Adeleke ti gbogbo ilu dìbò yàn.

Igbejo Idibo Osun

Iléẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye ètò ìdìbò ti fún Gómìnà Oyetola láṣẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun eèlò ìdìbò Osun

Ilé ẹjọ to n gbo awuyewuye eto idibo ni ipinlẹ Osun ti fún Gomina Oyetola l'ase lati ṣe ayẹwo awọn ohun eèlò ìdìbò ti wọn lo lasiko idibo to kọja.

Ilé ẹjọ to n gbo awuyewuye eto idibo ni ipinlẹ Osun ti fún Gomina Oyetola l'ase lati ṣe ayẹwo awọn ohun eèlò ìdìbò ní ajọ INEC.

Awọn agbẹjọrọ fun Gomina Gboyega Oyetola ti Agbejoro agba yomi Alliu saaju lo ṣalaye fun ile ẹjọ 'Tribunal' to n gbọ ẹjọ laarin Oyetola ati Adeleke pe wọn ko tii ri Ademola Adeleke fun ni iwe ipejọ bi o ti yẹ.

Kini o n ṣẹlẹ lori boya wọn ri iwe ipẹjọ fun Adeleke Ademola tabi bẹẹkọ?

Leyin ti awọn agbẹjọro Gomina Oyetola fidẹ mulẹ fun Adajo pe wọn ko ri Senato Ademola Adeleke lati fun un ni iwe naa bi o ti yẹ ni Adajo ba ni pe ki wọn lọ le iwe naa si ara fọto ipolongo ibo ti Adelekee ti wọn lẹ si ẹnu ọna ileejọ giga naa ni Oke fia ni Osogbo.

Àkọlé fídíò, ASUU Strike effect: Gbogbo à\won tó n ṣiṣẹ́ nítorí ileẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro wọn látìgbà

Alaga ile ẹjọ to n gbo awuyewuye nipa eto idibo gomina ni Ipinle Osun, Adajo Tertesa Aorga Kume ti pàṣẹ ki àwọn olujejo keji lo ọnà miran láti fí ìwé ipejo ranṣẹ sí gomina tuntun Ademola Adeleke.

Eyi waye nigba ti ikọ Oyetola sọ pe titi di isinyi, wọn koi tii ri Adeleke Ademola lati fun un ni iwe ipejo naa.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun

Adajo naa ni eyi wa lati lo lẹ mo ara patako iroyin to wa lenu ona ilé igbẹjọ idibo àti ṣíṣe ayẹwo àwọn ohun eèlò ìdìbò ni ile iṣẹ ajọ INEC.

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto ibo gomina ni ipinle Ọṣun lo ti sọ ṣáájú pe awọn yoo joko lọjọ Aje oni.

Sugbọn kii ṣe lati bẹrẹ igbẹjọ lori awuyewuye eto ibo gomina ipinlẹ Ọṣun laarin gomina Oyetọla ati Ajọ INEC pẹlu Sẹnetọ Ademola Adeleke.

Idibo Osun

Wo ibi ti igbẹjọ ajọ to n gbọ ẹjọ eto idibo nipinle Osun de duro.

Ijoko awuyewuye eto idibo ni ipinlẹ Ọsun ni ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, osu kẹjọ, ọdun 2022 ti sọrọ ṣaaju ki ijoko to pada bẹrẹ nigba to ba ya.

Nibẹ ni won yoo ti gbọ igbẹjọ ipenija ti igun Oyetọla gbe tọ ile ẹjọ naa wa lori ipenija ti wọn n koju lati fun Sẹnetọ Adeleke ni iwe ipẹjọ.

Lara awọn agbejoro agbà olupejo Yomi Alliyu (SAN) lakoko ti o n jiyan tọka sí àwọn igbenija ti awọn dojukọ lati mu ìwé ipejo tọ olujejo seneto Ademola Adeleke ti o sì rọ ile ẹjọ naa lati lo ọna míràn.

Àkọlé fídíò, Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn