Mó padánù ipò gómìnà nítorí ẹgbẹ́ òṣèlú márùn-ún parapọ̀ làti kojú APC lọ́dún 2019 ni ṣùgbọ́n....- Adelabu

aworan Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party ni ipinlẹ Oyo, Adebayo Adelabu ti sọrọ lori ibo 2019.

O ni pe ibo ti oun kojọ lọdun 2019 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progresive Congress, to fun oun lati bori idibo naa ti awọn ẹgbẹ oṣelu marun un ko ba parapọ lati koju ẹgbẹ oṣelu APC.

Adelabu, ẹni to dije labẹ asis ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lọdun 2019, sọ eleyi nigba ti o sọrọ lori redio kan niluu Ibadan.

O ni ẹgbẹ oṣelu PDP bori ibo gomina nitori wọn sisẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu marun un ni ipinlẹ Oyo.

“Awa Marun un la dije ti awọn mẹrin si gba lati sisẹ papọ lati koju ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2019.

“Wọn mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ma bori ibo naa ni wọn ṣe parapọ lati koju wa nigbayẹn, ko ki ṣe pe mi o le bori eto idibo.

“ibo toto ẹgbẹrun lọna ọgọtalelẹlọọdurun ni mọ kojọ lọdun 2019.”

Adelabu wa ransẹ ifinilọkanbalẹ si awọn ọlolufẹ rẹ pe iyato tuntun yoo de ba ipinlẹ Oyo laipẹ, nitori ẹgbẹ oselu Accord Party setan lati gba ise ijọba ipinlẹ Oyo.

O ni oun igbagbọ pe oun koju osuwọn lati tuko ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi gomina tuntun lọdun 2023.