Láti ìlú Owerri lá ti wá sí Ijebu Ode wá jalè- Omodé Afurasí mẹ́ta tí ọwọ́ tẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NPF
Boroboro l’awọn ọmọ kekeeke mẹta ti ẹ n wo yii n ka.
Ni kete t’ọwọ Amọtẹkun tẹ wọn n’ipinlẹ Ogun, iyẹn nibi ti wọn ti lọ digunjale, ti wọn si n bẹbẹ pe ki wọn f’oju aanu wo awọn.
Onyeneho Chukwuemeka, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Ibeh Dominion, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Adaya Stephen, ti oun naa jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun l’awọn ọrẹ mẹta t’ọwọ tẹ l’ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2022 ti a wa yii.
BBC YORUBA gbọ pe ilu Owerri to wa n’ipinlẹ Imo l’awọn mẹtẹẹta ti kuro pẹlu erongba lati lọ digunjale niluu Eko, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi niluu Ijẹbu-Ode.
Kini Amotekun sọ nipa iṣẹlẹ naa?
Alakoso fun ẹṣọ aabo Amọtẹkun n’ipinlẹ Ogun, David Akinrẹmi ln’igba to n f’idi iroyin ọhun mulẹ, o jẹ ko di mimọ pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii ni Chukwuemeka ati Dominion kuro niluu Owerri lati wa ohun ti wọn yoo jẹ lọ siluu Eko.
Akinrẹmi ni igba ti wọn de agbegbe Ojodu Berger ni wọn gba ile itura kan to wa ladugbo Lambẹ lọ lati sun oorun ọjọ mẹta gbako nibẹ, nibi ti wọn ti pinnu bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ wọn.
Lẹyin ti wọn kuro ni otẹẹli ọhun la gbọ pe wọn gba ilu Ijẹbu-Ode lọ l’ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ yii, nibi ti wọn ti ja ṣọọbu kan ti wọn ti n ta foonu, ṣugbọn ti wọn ko pada ri foonu kankan nibẹ. A gbọ pe ori orule ṣọọbu naa ni wọn gba wọle l’ọjọ naa.
Nibi ti wọn ti n wa ṣọọbu foonu miran ti wọn yoo ja, la gbọ pe wọn pade ẹnikẹta wọn, Adaya Stephen, ẹni ti wọn sọ pe ilu Warri, n’ipinlẹ Delta loun ti wa jale, ko to di pe wọn jọ gbimọ papọ.
Lọjọ ti wọn pade, a gbọ pe ṣe ni Adaya ko awọn mejeeji lọ sun nile akọku kan, nibi ti wọn sun si di alẹ patapata, ko ti di pe wọn dide lati lọ ja ṣọọbu miran ni nnkan bi agogo mọkanla aabọ alẹ, ọjọ kẹjọ, oṣu yii.
Ṣọọbu kan ti wọn ti n ta foonu, eyi to wa ladugbo Fọlagbade la gbọ pe wọn ja.
Bi wọn ṣe n jade ninu ṣọọbu ọhun, ọwọ awọn Amọtẹkun ni wọn ko si,, loju ẹsẹ si la gbọ pe wọn ti n rababa bẹbẹ pe ki wọn f’oju aanu wo awọn nitori pe iṣẹ eṣu ni.
Ni bayii, a gbọ pe awọn Amọtẹkun ti ko awọn mẹtẹẹta lọ f’awọn ọlọpaa ni Eleweran fun iwadii siwaju si i, ati lati le f’oju wọn ba ile-ẹjọ.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ bàbá ẹni ọdún 49 tó fún ọmọ ara rẹ̀ lóyún ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaadọta kan, Amoda Bola, ti ko si gbaga ọlọpaa ipinlẹ Ogun lori ẹsun pe o fun ọmọ ara rẹ loyun.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni ọmọ ọdun mẹrinla ni ọmọ rẹ ọhun.
Oyeymi ni ọwọ awọn tẹ afurasi naa, to n gbe ladugbo Oro, ni Ode Remo lẹyin ti ọmọ rẹ ọhun wa fi ẹjọ rẹ sun ni agọ wọn.
O ni “Ọmọ rẹ naa lo wa fi ọrọ naa lọ wa pe baba oun ti wọn ti jọ n gbe papọ fun ọpọ ọdun n ṣi oun laṣọ wo.”
“Ọmọ naa fi kun pe baba oun maa n pe awọn ọkunrin mii wa sinu ile wọn lati ba oun lopọ ti yoo si gba owo lọwọ awọn ọkunrin naa.”
Ni kete ti ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni wọn tẹkọ leti lọ si adugbo naa lati fi ṣikun ofin mu ọkunrin ọhun.
Nigba ti wọn n fi ọrọ wa lẹnu wo lagọ ọlọpaa, afurasin naa to kọkọ sẹ ẹsun ọhun pada jẹwo lẹyin ti ọmọ rẹ tako ọrọ rẹ.
Ọwọ tẹ awọn afurasi marun un mii
LAbimbola ẹyin iwadiii naa ni awọn ọlọpaa lọ fi ṣikun ofin mu awọn ọkunrin marun un mii to tun ba ọmọde naa lopọ lẹyin ti afurasi naa ke si wọn lati wa ṣe bẹẹ.
Orukọ awọn afurasi naa ni; Ahmed Ogunkoya, Muyiwa Adeoye, David Sunday Solaja, Emmanuel Olusanya ati Joshua Olaniran, ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọgbọn ọdun si ọdun mọkandinlaadọrin.

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, gbogbo awọn mararun yii lo ti jẹwọ pe lootọ ni awọn ti ba ọmọde naa lopọ, ti awọn si fun baba re lowo.
Wayi o, wọn ti wa gbe ọmọ ọhun lọ sile iwosan to wa ni Isara Remo bayii, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn tare ẹjọ naa si ẹka to n ṣewadii ẹsun to rọ mọ ọrọ ọmọde fun iwadii ni kikun ki awọn afurasi naa si le foju bale ẹjọ laipẹ.












