Àwọn obìnrin orílẹ̀èdè Iran tó nílò ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò ìbálé láti wẹ ara wọn mọ́ nílé ọkọ

Obinrin kan ati lori ibusun ninu yara

Oríṣun àwòrán, Manuella bonomi

Àkọlé àwòrán, Maryam gbiyanju lati ṣalaye idi ko fi ri ẹjẹ abale rẹ bi o tilẹ jẹ pe ko ọkunrin kankan ni ibalopọ ri ṣugbọn ọkọ rẹ ko gba

Lorilẹede Iran, jijẹ wundia ṣaaju igbeyawo jẹ ohun to ṣe pataki fun ọpọ awọn ọdọmọbinrin ati idile wọn pẹlu.

Lọpọ igba lawọn ọkunrin maa n beere fun iwe ẹri wundia wọn, ajọ ilera agbaye si ti tọka si aṣa yii gẹgẹ bi eyi to tako ẹtọ ọmọniyan. Amọṣa, bi ọdun ṣe n gori ọdun lọpọ awọn eeyan naa ti n darapọ lati dide tako aṣa naa.

"O fi ẹta mu mi fẹ ẹ nitori pe mo ro pe wundia ni ẹ. Ko si ẹni ti yoo fẹ ẹ mọ bi mo ba tu aṣiri sita."

Eyi lọrọ ti ọkọ Maryam sọ sii lẹyin ti wọn ni ibalopọ fun igba akọkọ lẹyin igbeyawo wọn.

Maryam gbiyanju lati ṣalaye fun pe lootọ ẹjẹ abale oun ko da sita gẹgẹ bi o ṣe yẹ ko ri lọpọ igba, ṣugbọn oun ati ẹnikẹni ko ni ibalopọ ri. Ṣugbọn ọkọ rẹ ko gba, o ni afi ko lọ mu iwe ẹri wundia rẹ wa.

Eyi kii ṣe ohun ajeji lorilẹede Iran. Lẹyin ti awọn obinrin ba ti ni afẹsọna lorilẹede naa, ọpọlọpọ wọn lo maa n lọ si ọdọ dokita iṣegun oyinbo lati gba iwe ẹri pe wundia ṣi ni wọn ati pe wọn ko mọ ọkunrin ri.

Amọṣa o, ajọ ilera lagbaye, WHO ti sọ pe ko si ẹri imọ ijinlẹ oyinbo to gbe eto ayẹwo wundia lẹyin.

Iwe ẹri wundia ti Maryam gba ṣalaye pe ibale rẹ jẹ eyi to leefa bi rọba eyi to tumọ si pe o ṣeeṣe ki ẹjẹ maa jade bi wọn ba ja abale rẹ lasiko ibalopọ.

"O jẹ ohun to ba mi ninu jẹ pupọ. Mi o ṣe ohun aida, ṣugbọn ọkọ mi n fi gbogbo igba sọrọ abuku si mi. Nigba ti mi o lee muu mọra mọ ni bo ba binu gbe ogun jẹ lati pa ara mi"

Wọn gbe e lọ sile iwosan nibi ti wọn ti doola ẹmi wọn.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu obinrin Naijiria to n gbe Morocco

Bi ipe ṣe n dide fun fifopin si aṣa yii

Iriri Maryam ṣe apẹrẹ ohun ti oju awọn obinrin n ri lorilẹede Iran. Jijẹ wundia ṣaaju igbeyawo ṣi jẹ ohun kan to ṣe pataki ninu eto igbeyawo fun ọpọlọpọ ọdọbinrin ati ẹbi wọn lorilẹede Iran.

Amọṣa, lẹnu lọwọlọwọ yii ipe ti n lọ lọpọlọpọ fun ayipada aṣa yii. Ọpọ ọkunrin ati obinrin jakejado orilẹede naa ni wọn ti n sọrọ soke fun fifopin si aṣa ayẹwo ibale obinrin.

Loṣu kọkanla ọdun to kọja, ileeṣẹ kan to n gba iwe ẹbẹ ẹhonu lori ayelujara ti gba iwe ẹhonu to fẹrẹ to ẹgbẹrun marundinlọgbọn laarin oṣu kan.

Nigba ti Neda jẹ akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọrẹkunrin rẹ ti ja abale rẹ nilu Tehran.

"Aya mi n ja, ẹru n ba mi lori ohun to lee ṣẹlẹ bi awọn ẹbi mi ba mọ."

Nitori eyi, Neda pinnu lati tun ibale rẹ ṣe pada.

Obinrin kan n san owo fun ọkunrin kan

Oríṣun àwòrán, manuella bonomi

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo lorilẹede Iran awọn kii ṣa dede ṣe ayẹwo ibale fun awọn ọlọmọge bi ko ba ni idi kan pato to ṣe pataki

Nitori awọn idẹyẹsi to rọ mọ eyi lawujọ, ko si ileewosan to fẹ lọwọ ninu rẹ.

Nigba ti Neda ri ileewosan aladani kan ti yoo ti ṣe eyi ni idakọnkọ, amọṣa owo gọbọi lo ba de.

Awọn ohun ini rẹ bii ẹrọ kọmputa alagbeka, fonu ibanisọrọ rẹ ati goolu olowo iyebiye lo ta.

Lẹyin to tọwọ bọwe adehun kan, ni wọn bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ atunṣe ibale rẹ naa.

O gba wọn ni ogoji iṣẹju , ṣugbọn ọpọ ọsẹ ni Neda lo ko to ni ilera pipeye pada.

"Irora nla ni mo la kọja. Mi o lee gbe ẹsẹ mi."

Lẹyin ọdun kan, Neda pade ẹni ọkọ. Amọṣa nigba ti wọn ni ibalopọ, ẹjẹ ibale koyọ o.

"Ọkọ mi fi ẹsun kan mi pe mo fi tan oun wọ inu igbeyawo. O ni onirọ ni mi. O si ja mi ju silẹ."

Ikayasoke awọn mọlẹbi

Pẹlupẹlu gbogbo bi ajọ eto ilera lagbaye, WHO ti ṣe pariwo sita tako aṣa ṣiṣe ayẹwo ibale obinrin gẹgẹ bi eyi ti ko ba igba mu ti ko si ni ifidimulẹ kankan ninu imọ ijinlẹ sayẹnsi, aṣa yii ṣi n tẹ siwaju lọpọlọpọ orilẹede bii Indonesia, Iraq ati Turkey.

Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo lorilẹede Iran awọn kii ṣa dede ṣe ayẹwo ibale fun awọn ọlọmọge bi ko ba ni idi kan pato to ṣe pataki bii ti ọrọ ba di ọrọ ile ẹjọ tabi ẹsun ifipabanilopọ..

Amọṣa ọdọ awọn lọkọlaya to ti gbe ara wọn niyawo ni pupọ ẹbẹ fun iwe ẹri ayẹwo ibale obinrin to n jade tọ awọn dokita iṣegun oyinbo ti n wa.

Awọn ileewosan aladani ni wọn si maa n lọ- iya wọn yoo si tẹle wọn lọ. Akọṣẹmọṣẹ nipa itọju ara obinrin tabi agbẹbi ni yoo ṣe ayẹwo naa ti yoo si kọ iwe ẹri naa fun wọn. Lara awọn ohun ti yoo wa lori iwe ẹri naa ni orukọ obirin naa, orukọ baba rẹ, nọmba idanimọ rẹ lọdọ ijọba ati fọto rẹ nigba miran.

Iwe ẹri naa yo ṣe apejuwe ipo ti ibale rẹ wa, yoo si tun kọ ọ si pe "Wundia ṣi ni ọmọdebinrin yii."

Obinrin kan n ṣe ayẹwo obinrin miran ti awọn obinrin meji si n wo wọn

Oríṣun àwòrán, Manuella bonomi

Àkọlé àwòrán, Awọn ileewosan aladani ni wọn si maa n lọ- iya wọn yoo si tẹle wọn lọ.

Ọkan lara awọn dokita to ti n fun awọn eeyan ni iwe ẹri ayẹwo ibale ni Dokita Fariba jẹ. O ni ko si aniani pe aṣa to tiniloju pupọ ni, amọṣa o ni igbagbọ oun ni pe iranlọwọ loun n ṣe fun ọpọlọpọ awọn obinrin.

"Wahala awọn mọlẹbi wọn pọ. Nigba miran, maa fi ẹnu lasan pa irọ fun awọn lọkọlaya naa. Bi wọn ba ti ba ara wọn sun ti wọn si fẹ gbe ara wọn niyawo, maa sọ ọ niwaju awọn mọlẹbi wọn pe wundia ṣi ni ọmọbinrin naa."

Amọ o, ọpọlọpọ awọn ọkunrin lo ṣi n poungbẹ lati fẹ obinrin ti wọn ko tii ja abale rẹ.

Ali oniṣẹ ọwọ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn sọ pe Shiraz sọ pe, "Bi obinrin ba ti padanu ibale rẹ ṣaaju igbeyawo, wọn ko lee fi inu tan an. O lee fi ọkọ rẹ silẹ lọ fẹ ẹlomiran.

O ni oun nitoun ti ni ibalopọ pẹlu obinrin mẹwaa nitori pe oun ko le mu ara duro.

Ali gba pe iwa abosi pata gba ni aṣa orilẹede Iran naa ṣugbọn oun ko fẹ tapa si aṣa awujọ oun.

Ọpọ awọn eeyan lorilẹede Iran, paapaa lawọn ileto kerejekereje, ni wọn fara mọ ohun ti Ali sọ.

Ki ni ireti ọjọ iwaju?

Lẹyin ọdun mẹrin to gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ to ṣi tun ṣi n gbe pẹlu ọkọ rẹ to n fi iya ati abuku kan an, lẹyin o rẹyin Maryam ti lanfani lati kọ ọkọ rẹ silẹ nile ẹjọ.

Lọsẹ diẹ sẹyin lo di apọn pada.

Àkọlé fídíò, Sleep paralysis: Kò sí òkú tàbí aǹjọ̀nú ró n lé ọ lójú oorun- Olajide Obembe

"Yoo nira fun mi gidi lati gbẹkẹ le ọkun lẹyin eyi o. mi o si ro pe mo lee tun ni ọkọ mọ lọjọ iwaju."

Pẹlu omilẹgbẹ awọn obinrin miran, Maryam pẹlu ti di ọkan lara awọn ami ẹhonu tako aṣa yii lori ayelujara.

Bi o tilẹ jẹ pe ko reti ki ayipada de laipẹ, koda ni igba aye rẹ, amọṣa o ṣi n ni igbagbọ pe awọn obinrin yoo lanfani kan naa pẹlu awọn ọkunrin lorilẹede naa laipẹ jọjọ.

"Mo mọ pe yoo waye lọjọ kan. Mo ni ireti pe lọjọ iwaju, ko ni si ọdọbinrin ti yoo la ohun ti mo la kọja kọja."

A ṣe ayipada gbogbo orukọ ti a lo ninu akọsilẹ iroyin yii lati daabo bo awọn eniyan ti ọrọ kan.

Bi o ba n la eyikeyi ohun ti a mẹnuba ninu akọsilẹ iroyin yii kọja, jọwọ kan siBBC Action for Support