Nítorí iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe, Mary ta ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ní N600:000 ni Mowe
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ iyaale ile, ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Mary Ọlatayọ, lori ẹsun wi pe o ta ọmọ rẹ, ọmọ ọsẹ mẹta to bi ninu.
Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii la gbọ pe ọwọ palaba Mary segi, lẹyin ti ọkọ rẹ lọ fi ẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Mowe.
Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira ni Mary ta ọmọ naa danu, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to fi iroyin ọhun ranṣẹ si BBC YORUBA lọsan oni, o fi ye wa pe ile itura kan lọwọ palaba Mary ti segi, nibi to ti lọ ṣiṣẹ aṣẹwo.
Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ sọ pe "Baba ọmọ naa lo wa si teṣan ọlọpaa Mowe, to si ṣalaye wi pe oun pade Mary Ọlatayọ nigba pipẹ diẹ sẹyin, ti awọn si bẹrẹ sii fẹ ara wọn.
"Ọmọkunrin naa ni lẹyin ti Mary loyun f'oun, loun pinnu lati gba ile tuntun fun un lati maa gbe, ibẹ lo si wa titi to fi bimọ ọkunrin.

Oríṣun àwòrán, @NPF
Ileeṣẹ ọlọpaa ni pe: "O ni lẹyin ọsẹ mẹta ti Mary bimọ naa tan lo poora lojiji, to si jẹ pe otẹẹli to ti lọ ṣiṣẹ aṣẹwo l'awọn ti pada ri i pẹlu ọkunrin miran.
"Bi wọn ṣe ri Mary lo beere ọmọ naa lọwọ ẹ, ṣugbọn ti wọn lo sọ pe oun ko le ṣalaye ibi ti ọmọ naa wa."
Oyeyẹmi sọ pe ẹsun yii lo tẹ ọga ọlọpaa ẹkun Mowe, Fọlakẹ Afẹnifọrọ lọwọ, to fi gbe igbesẹ labẹ ofin, ti wọn si pada lọ gbe Mary ni otẹẹli ọhun.
Nigba to l'awọn n f'ọrọ wa a lẹnu wo lo ṣẹṣẹ jẹwọ pe oun ti ta ọmọ naa danu fun ẹnikan to wa n'ipinlẹ Anambra, ati pe ẹgbẹta naira loun ta a
Kini Mary Olatayo so?
Mary tẹsiwaju pe ọrẹ oun kan to n je Chioma Esther Ogbonna, ọmọ bibi ipinlẹ Imo lo mu oun lọ sọdọ ẹni to ra ọmọ naa lọwọ oun, ti awọn si pin owo rẹ lọgbọọgba.
Eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa lọ gbe ọrẹ naa, iyẹn Chioma Esther Ogbonna, toun naa si jẹwọ pe lotitọ ni.
Iwadii ọlọpaa pada f'idi rẹ mulẹ pe iṣẹ oloṣo paraku ni Mary Ọlatayọ, ọmọ bibi ilu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara yan laayo, to si ri ọmọ naa gẹgẹ bi idiwọ fun iṣẹ oun, eyi to jẹ ko ta a danu.
Oyeyẹmi ti wa jẹ ko ye wa pe ọga awọn, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii fifi ọmọ ṣoowo ẹru gba iṣẹ iwadii naa ṣe, lati ri i pe wọn ri ọmọ naa gba pada.

Oríṣun àwòrán, others
À kò jẹ́ ẹnikẹ́ni lówó oṣù ọdún kàn - Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ni awọn kọ ni awọn gba awọn ọlọpaa kan ti wọn ṣe ifẹhonuhan lori ayelujare sisẹ tori naa awọn ko jẹ wọn ni owo kankan.
Ninu atẹsita kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Okasanmi Ajayi fi ransẹ si awọn akọroyin, , Kọmisani ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, CP Tuesday Assayomo psc (+), ni awọn ọlọpaa ti wọn ṣe ifẹhonuhan naa ni wọn jẹ oluranlọwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lati peṣe abo si origun mẹrin ipinlẹ na.
O tẹsiwaju pe, gbigba awọn ọlọpaa naa ni ko ni adehun owo ninu, ti wọn si ti bawọn sọrọ ki wọn to bẹrẹ isẹ.
Assayomo ni igbati ariwo awọn ọlọpaa naa pọ ni awọn fi to eti ijọba ipinlẹ Kwara, ti wọn si ni ki wọn yooju si ile jọba loni lati mu ohun ti ijọba lero fun wọn.

Oríṣun àwòrán, others
“O yawa lẹnu pe awọn ọlọpaa ni ileeṣẹ ọlọpaa jẹ awọn lowo ọdun kan,
“A n pe akiyesi awọn olugbe Kwara si ọrọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ko jẹ obinrin, ọkunrin ni owo fun isẹ ti wọn ṣe lọfẹ fun ipinlẹ Kwara.
“Fun idi eyi, a rọ yin lati yago si fifi ọlọpaa wọlẹ lori ayelujara
Okesanmi ni awọn ko fi tipatipa mu ẹnikẹni lati ṣe isẹ ọfẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ati pe wọn ni anfani lati ni awọn ko ṣe mọ.
“Ti o ba wu wọn, wọn fi ise naa silẹ nitori a ko fi tipatipa mu ẹnikẹni si.”















