Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni pé mo buwọ́lu Tinubu fún ipò Ààrẹ -Obasanjo

aworan Tinubu ati Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi

Aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti rọ awọn alaatilẹyin oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lati dẹkun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri pe oun ti buwọlu Tinubu.

Obasanjo, ẹni ti Tinuba ṣe abẹwo sile rẹ niluu Abeokuta losẹ to kọja, ni ipade ọlọrẹ lo waye laarin awọn mejeeji, ti ko si jẹ mọ ọrọ oṣelu tabi ọrọ eto idibo ọdun 2023.

Ninu atẹsita kan ti Agbẹnusọ rẹ, Kehinde Akinyemi fun awọn akọroyin, Aarẹ tẹlẹ ni ọrọ ti o tẹnu awọn alaatilẹyin Tinubu jade ni ko ṣe iranwo fun ẹnikẹni.

“Ipade ọlọrẹ sọrẹ lo waye, ki n ṣe ipade ọrọ oṣelu.”

“Emi ko ti ṣo boya Tinubu lokan tabi ẹlomiiran.

“Gbogbo ẹyin ti n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri pe mọ nkan ti mi sọ ni ko ṣe irankọwọ kankan fun ẹnikẹni.

Tinubu sabẹwo si Aarẹ tẹlẹ naa nile rẹ niluu Abuja lọjọru ọsẹ to kọja pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress.

Awọn mii ni olori ile aṣojuṣofin lorilẹede Naijiria, Họnọrebu Gbajabiamila, awọn gomina ipinlẹ Ogun nigba kan ri, Oluṣẹgun Ọṣọba ati Gbenga Daniel.

Pẹlu gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun atawọn eekan miran lẹgbẹ oṣelu naa.

Bakan naa lawọn Ọbalaye kannrin-kannrin nilẹ Yoruba pẹlu wa nibi ipade naa.