Ẹgbẹ́ SSANU àti NASU fi òpin sí ìyanṣẹ́lódi

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn ile ẹkọ giga fasiti to n bẹ loriẹede yii labẹ asia SSANU ati awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ, NASU ti fi opin si iyansẹlodi lẹyin ti wọn ṣe ipada pẹlu Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria.
Minisita fun eto ẹkọ, Adamu Adamu ni ijọba apapọ ti ṣeto owo toto adọta bilọnu naira fun awọn ọmọ ẹgbẹ SSANU, ASSU ati NASU.
Sugbọn awọn ile ẹkọ si ma wa ni titipa nitori Ajọ ASSU si n tẹsiwaju pẹlu iyanselodi wọn
Minisita tẹsiwaju pe lati ọjọbọ ọsẹ to kọja ni ajọ SSANU ati NASU ti gba lati fi opin si iyansẹlodi, sugbọn ti ajọ ASSU kọ lati fi opin si iyansẹlodi.
Ninu atẹsita kan ti awọn ajọ SSANU ati NASU fi sita fun awọn akọroyin, wọn ni osu meji ni awọn fun ijọba lati yanju gbogbo awọ to ba laarin wọn.
“Osu meji yii ni a fun ijọba lati ṣe ohun to ye ki wọn ṣe.”
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Peter Adeyemi ni ipsde ti wọn pẹlu ijọpa apapọ ni ki wọn ya owo toto adọta bilọnu naira sọtọ fun ajẹmọnu awọn ọmọ egbẹ naa.
“Minisita ni oun ti pa ika to risi fasiti (NUC) lasẹ lati ri pe wọn ṣe ohun to tọ si gbọgbo fasiti lorilẹede Naijiria.
“Minisita fun eto ẹkọ ni wa fi da wa loju pe ijọba ko ni fitina ọmọ ẹgbẹ to gun le iyansẹlodi ti wọn fi opin si yii.
“ Minsita Adamu ni Aarẹ Buhari si n tẹle adehun rẹ pe ida mẹdogun ninu ọgọrun lo wa fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria.















