Ọwọ́ ti tẹ́ bàbá ọmọ to pa ìdí pọ̀ pẹ̀lú nọ́ọ̀sì láti ta ọmọ ọṣu mẹ̀ta rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọwọ ti tẹ baba ọmọ kan, dokita rẹ ati nọọsi kan ti wọn jọ gbimọ pọ lati ta ọmọ oṣu mẹta nipinlẹ Eko.
Awọn afurasi ti ọwọ tẹ yii fẹ ta ọmọ jojolo naa gbẹ lẹyin ti wọn ji lai si imọ iya rẹ ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ loju opo Twitter rẹ.
O ni lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti iya ọmọ naa ti n wa ni o fi to ọlọpaa leti.
Gbogbo awọn afurasi patapata ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi panpẹ ọba mu.
Bakan naa ni wọn fikun un pe alaafia ni ọmọ naa wa lai si ewu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹka SCID ni yoo sakoso igbẹjọ iṣẹlẹ naa.
Akẹ́kọ̀ọ́ fásìtì Oye Ekiti tó ń sojú NANS rí ẹ̀wọ̀n he lórí ẹ̀sùn jìbìtì ₦195m

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Akẹkọọ kan ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Oye Ekiti, to tun jẹ ọkab lara awọn adari ẹgbẹ akẹkọọ, NANS, Adeyemi Israel Abiodun ti ri ẹwọn ọdun kan he lẹyin to jẹbi ẹsun lilu jibiti ori ayelujara.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Najiiria, EFCC lo fẹsun kan akekọọ naa atawọn mọkandinlogoji mii niluu Ibadan lori jibiti.
Ninu atẹjade kan ti EFCC fi lede loju opo Twitter rẹ, wọn ni iye owo jibiti akẹkọọ naa, atawọn ẹmẹwaa rẹ jẹ miliọnu marundinnigba naira.
Atẹjade naa ni “O wa lara awọn ogoji afurasi to kawọ pọn rojọ niwaju awọn adajọ kan nile ẹjọ giga to wa niluu Ibadan.”
“Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni gbigba owo lọwọ awọn eeyan pẹlu ọna ẹburu, gbigba dukia ẹlomiran pẹlu irọ pipa, ati iwe yiyi eyii to lodi si abala 419, 467, 484, 516 ofin Naijiria ati abala 508 ofin ipinlẹ oyo.”
Awọn mọkandinlogoji mii mtu foju bale ẹjọ
Yatọ si akẹkọọ yii, awọn afurasi mii to tun foju bale ẹjọ ni Yekeen Azeez Ishola, Okeniyi Sanuel Akiniyi, Theophilus Ademola Bukola, Salami Mohammed Adetayo, Pelumi Ajayi Temiloluwa, Lawal Abdullateef Olalekan, Okusanwo Mayowa Daniel, Oluwole Oluwasegun Ayomide, Adedotun Omodele Yusuf, Monday Nnaemeka Samuel, Idowu Adeshina ati Olowe Nifemi Ayomide.
Awọn wọn yii naa tun foju bale ẹjọ: Adubu Olamiotan Sunday, Kehinde Olatunji Kehinde, Oguntuase Tope Francis, Elijah Isaac Wisdom, Ogbanaya Chukwu Chukwu, Adekola Adekunle, Odebode Temiloluwa Kehinde, Joseph Odunayo Clement,Andrew Adekunle Masika, Usman Mubarak Damilare, Isiaka Olumide Hammed, Uawu Osita Henry, Kareem Afeez Alabi ati Ogunyemi Ayobami Samuel.
Awọn to ku ni Mimiola Victor Olamide, Adeeko Kolade Emmanuel, Egberongbe Adedayo Quam, Oyelaran Olayiwola Jeremaih, Hammed Rilwan Ishola, Adefowora Omotayo David, Adedeji Ibrahim Olamilekan, Emmanuel Timileyin Akinbowale, Michael Damola Olanrewaju, Ayanyemi Olaide Samuel, Boye Timilehin Emmanuel, Timileyin Ajibola Idowu and Azeez Tolulope Ayoade.
Ẹwẹ, akẹkọọ naa atawọn afurasi ẹgbẹ rẹ sọ niwaju adajọ pe awọn gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn kan awọn.












