Èmi kò torí owó fún Portable lóyè o, torí ìwà ọmọlúwàbí rẹ̀ ni - Onitigbo of Tigbo-Awori

Oríṣun àwòrán, portable zhe/Instagram
Kabiyesi Onitigbo ti ilu Tigbo-Ilu, Ọba Ọlabọde Thomas-Fagbayi ti sọrọsoke leyin to fun Portable loye.
O ṣalaye pe, lodi si ohun ti ọpọ n sọ kaakiri pe nitori owo loun ṣe fi oye da gbajumọ akọrin takasufe, Habeeb Okikiọla ti ọpọ mọ si Portable lọla.
Ọba Thomas-Fagbayi ṣalaye pe iwa irẹlẹ ati ọmọluwabi ti oun ri lara Portable lo mu ki oun fi oye ilu Tigbo-Ilu daa lọla.
Lọjọ Aje ni Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable jẹ oye Amuludun ilu Tigbo ni Awori.
Gbajumọ olorin naa ko si lee pamọ sara rara, lo fi gba oju opo ayelujara rẹ gbogbo lọ lati kede fun awọn ololufẹ rẹ pe oun ti di baba oloye tuntun ni Awori.
Lati igba ti ayẹyẹ naa ti waye ni ọpọ onwoye ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ọbalaye naa gbe
Ohun ti wọn n sọ ni pe pẹlu oniruru iroyin aṣemaṣe to n jade nipa akọrin naa, ko yẹ ki Kabiyesi Onitigbo fi oye ilu da a lọla.

Oríṣun àwòrán, Portable zhe/Instagram
Amọṣa nigba to n fesi lori awọn ikunsinu naa, Ọba Thomas-Fagbayi ni igba kan wa ti oun gbọ pe awọn eeyan kan fara sese nitori akọrin kan ti wọn ni o n fọn owo kiri.
Oun ni ki wọn sọ fun un pe ko wa ri oun. Igba meji ni ọba Thomas-Fagbayi salaye pe igba meji ọtọtọ ni Portable wa ti ko ba oun.
“ Lọjọ kan ti mo n lọ ni igboro ni mo tun rii to n lọ ninu okọ rẹ, ni mo ba pe e. O jẹ mi ni oo pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ.
Gbalaja ni gbogbo wọn si dọbalẹ ni iwaju mi loju popo ti mo wa.”
Ọba Onitigbo tun ṣalaye pe, Portable kii ṣe atọhunrinwa nilu Tigbo Awori nitori ọmọ ilu naa ni iya rẹ jẹ.












