Pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo ní orílẹ̀-èdè Ukraine fí ń ṣé ayẹyẹ àyájọ̀ òmìnira

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ayẹyẹ ayajọ ominira ni o jẹ ọjọ nla lorilẹ-ede Ukraine ti awọn ọmọ ologun si maa n mu inu ọpọ araalu dun sugbọn ọrọ ba ibo miiran yọ lọdun yii.
Ayajọ naa ni ko le waye lọdun yii nitori ikọlu ati ogun to n lọwọ pẹlu orilẹ-ede Russia.
Ijọba orilẹ-ede Ukraine ni awọn ni igbagbọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ologun orilẹ-ede Russia ṣe ikọlu si Khreshatik, ti wọn si ti sọ kọkọrọ si gbogbo pupọ lara awọn ibi igbafẹ lati ọjọ mẹji sẹyin.
Wọn wa rọ awọn araalu lati gbọ ikilọ ijọba, ki wọn si ṣe ni oju ni alakan fi n sọri.
Bakan naa, o ni lo pe osu kẹfa ti awọn ọmọ orilẹ-ede Russsia ti bẹrẹ ikọlu si orilẹ-ede Ukraine.
Ibẹrubojo wa peleke si lẹnu ọjọ mẹta lẹyin ti ado olorun dundun waye ni agbegbe Crimea ati bi wọn ṣekupa sọrọsọrọ oṣelu, Daria Dugina lẹ Moscow ni opin ọsẹ.

Oríṣun àwòrán, EPA
Nigba ti o ba awọn araalu sọrọ, Aarẹ Zelensky ṣe ikilọ pe orilẹede Russia yoo si fi ado oloro ransẹ si awọn ibudo kan sugbọn awọn ti setan fi koju awọn ọpmọ ologun naa.
Ogun Russia ati Ukraine ti ṣekupa ọpọlọpọ eniyan, ajọ United Nation ni o to ẹgbẹrun marun un eniyan to ba ogun naa lọ
sugbọn o ju bẹẹ lọ ati pe ọpọ awọn olugbe ilu naa fi wọn ti sa kuro ni ile wọn.
Lowọlọwọ bayi, ogun naa si n tẹsiwaju ati ko si si ami pe yoo wa sopin laipẹ.
Wó àwọn ohùn tó wáyé láàrín oṣù mẹ́fà tí ógun tí bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọjọ kẹrinlelogun, osu keji (24 February): Lẹyin ọpọlọpọ awuyeawuye, ọjọ kẹrinlelogun ni Aarẹ Russia, Vladimir Putin bẹrẹ ki kọlu orilẹede Ukraine pẹlu erongba lati gba isakoso awọn ọmọ ologun lorilẹede Ukraine
Ọjọ keje osu kẹta (7 March): Ọjọ ti orilẹede mejeeji gba lati si enu ibode Mariupol lati fun awọn araalu laye laye kuro niluu sugbọn ko pada waye nitori idunkoko orilẹede Russia si n tẹsiwaju.
Ogbọnjọ osu kẹta (30 March): Orilẹede Russia kede pe awọn yoo dẹkun ikọlu si Kyiv sugbọn awọn gbe ogun lọ si ila oorun orilẹede Ukraine.
Ọjọ kini, osu kẹrin (1 April): Ogunlọgbọn oku ni wọn ri ni awọn opopona Bucha lẹyin ti awọn orilẹede Ukraine ṣe ikọlu si bẹ, ti wọn si ṣeku pa awọn eniyan.
Ogunjọ osu karun (20 May): Orilẹede Russia gba isakoso ileeṣẹ irin Azovstal niluu Mariupol.
Ọjọ kedọgbọn osu kẹfa (25 June): Apa iwọ oorun Severodonetsk bọ si ọdọ orilẹede Russia pẹlu alamuleti wọn Lysychansk ni ọjọ kẹta osu keje, eyi to fun Moscow lati igba isakoso iwọ oorun Luhansk.
Ọjó kini osu kẹjọ (1 August): Ọkọ ojuomi gbera lati orilẹede Russia pẹlu erongba lati lọ koju orilẹede Russia.















