Àwọn ‘Rev. Sister’ mẹ́rin tí wọ́n jígbé tí gba ìtúsílẹ̀

Awọn sister mẹrin ti ijọ Jesus the Saviour Generelate, ti ijọ Aguda ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe to ji wọn gbe ni oju ọna Okigwe-Umulolo ni ijọba ibilẹ Okigwe ni ipinlẹ Imo.

Awọn sister mẹrin naa ti orukọ wọn n jẹ Johannes Nwodo, Christabel Echemazu, Liberata Mbamalu ati Benita Agu ni wọn n lọ fun isin idupẹ ti wọn si ra wọn mu.

Amọ, Akọwe ile ijọsin naa ti fi iroyin lede pe wọn ti tu wọn silẹ, ti awọn to ji wọn gbe ko si gba nkankan lọwọ wọn.

‘’Pẹlu idunnu ati ayọ ni a fi kede pe awọn sister wa mẹrin ti wọn jigbe ti gba idusilẹ’’

‘’O jẹ ọjọ manigbagbe fun wa, ti a si fẹ ki gbogbo eniyan ba wa yọ ayọ paapaa awọn to gbadura fun itusilẹ awọn akẹgbẹ wa ninu Oluwa naa.’’

Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ awọn ọmọ lẹyin Kristi to duro ti wọn lasiko ti wọn ji awọn obinrin naa gbe lọ.

Bí àwọn agbẹ́bọn ṣe jí àwọn sister mẹrin gbé lọ nìyíí...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Awọn agbebọn tun ti ṣekọlu si awọn arinrinajo ni opopona Okigwe si Enugu, ti wọn si ji awọn sister mẹrin gbe lọ.

Ninu atẹjade ti Ile ijọsin The Sisters of Jesus the Saviour fi lede ni wọn ti salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Ninu atẹjade ti wọn pe akọle rẹ ni iroyin ibanujẹ ni wọn ti darukọ awọn sister mẹrin ti wọn jigbẹ lọ naa.

Ile Ijosin naa ni awọn fi iroyin naa to awọn ọmọlẹyin Kristi leti, ki wọn le fi adura ran won lọwọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, SCREENGRAB

‘’Ni Ọjọ Isinmi ti wọn n lọ fun isin lati ipinlẹ Rivers lọ si Imo fun isin idupẹ ki wọn to ji wọn gbe lọ.’’

‘’Ẹyin ara ninu Kristi ni a fi ibanujẹ lọpọlọpọ sọ fun yin pe wọn ti ji awọn arabinrin wa mẹrin gbe lọ lasiko ti wn n lọ fun isin ni agbegbe Okigwe si Umulolo ni wọn ti gbe wọn lọ.’’

A fi asiko yii pe fun adura kikan kikan ki wọn tu wọn silẹ lai si ibi.

A dura ki Maria, iya wa wa pẹlu wọn ki wọn si fi wọn silẹ laipẹ.

Iwadii fihan pe oju popo naa ni ọpọlọpọ iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ tẹlẹ ri, to fi mọ Prelate ijọ Methodist Church of Nigeria, Samuel Kanu-Uche ti wọn jigbe ni Oṣu Kẹfa,ọdun 2022.