Ìjàmbá ọkọ̀ mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́fà lọ l’Ondo, mẹ́rin dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Babafemi Alonge
Ọjọ buruku eṣu gbomimu ni nilu Ajuẹ ni popona ilu Ondo si Ore nipinlẹ Ondo.
Eyii ko ṣẹyin bi eeyan mẹfa ṣe padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ kan to waye nibẹ.
Awọn ti iṣẹlẹ laabi naa ṣoju ṣalaye pe ọkọ ajagbe kan to ni nọmba MUS 321 YF lo padanu ijanu ọkọ rẹ, leyi to mu ko ya bara lọ kọlu ọkọ bọọsi kan pẹlu nọmba RGB 487 XA ti awọn mẹwa wa ninu rẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe ẹmi eeyan mẹfa ninu awọn mẹwaa to wa ninu ọkọ lo bọ lẹsẹkẹsẹ.
Awọn mẹrin to ku ninu ọkọ naa awọn ẹṣọ oju popo ri aye doola ẹmi wọn ti wọn si gbe lọ ile iwosan ni kiakia pẹlu iranwọ awọn to wa lagbegbe ọhun.
Adari ajọ ẹṣọ oju popo lagbegbe Ore, nipinlẹ Ondo, Babafemi Alonge, to fidi ọrọ naa mulẹ sọ pe aini suuru lo fa ijamba ọkọ naa.
Alonge fi kun pe awọn mẹfa ti wọn dagbere faye ninu ijamba ọkọ ọhun lo ti wa nile igbokupamọsi bayii.
Awọn mẹrin ti ori ko yọ ti wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.












