Lẹ́yìn tí ilé wò pá ẹni méjì, Ìjọba Eko kéde gbèndéke ọjọ́ méje fún àwọn olùgbé tókù níbẹ̀

aworam

Ajọ to n risi ọrọ ile nipinlẹ Eko, LABSCA ti kede gbedeke ọjọ meje fun awọn olugbe ilegbe kan ni agbegbe Adeleye ni Bariga lati ko kuro nile lẹyin ti iṣẹlẹ ile wiwo seku pa eeyan mẹji lọjọ aiku ọsẹ yii.

Isẹlẹ naa lo waye lẹyin ti tanka omi wo lati ninu ile kan si omiiran, ti o si seku pa eeyan meji lẹsẹkẹsẹ.

Ọkan lara awọn olugbe ile oun, Sunday Hassan, ni iyalẹnu ni iṣẹlẹ naa nitori Ọlọrun lo ko ọpọlọpọ yoo ninu ile naa.

Hassan ni oun pẹlu awọn miiran lo gbinyanju lati yoo awọn to farapa kuro labẹ ile nigba ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ.

“Ninu ile ni mo wa, ti mo kan gbọ gba, ko pe ni mo n gbọ gbamii o, sugbọn ki a to de ibẹ, a ti ba oku eeyan meji nile ati awọn miiran to farapa.

aworan

“Arabinrin pẹlu ọmọ ati aburo rẹ lo wa ninu yara ti tanka naa wo le.”

Ọmọ ati aburo si ti gbẹmi mi lẹsẹkẹsẹ sugbọn arabinrin oun a nile wosan.

Hassan wa ni awọn ajọ to riri iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ti fun awọn olugbe ile naa ni gbedeke ọjọ meje lati fi ko kuro nille nitori ijamba ọjọ iwaju.

“Awa naa mọ pe ijọba fe dola ẹmi awa yoo ku ni.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

''Tank'' omi jábọ́ lórí ilé, ènìyàn méjì gbẹ́mí mì, mẹ́ta farapa

Eniyan meji ti gbẹmi mi, ti mẹta si farapa lẹyin ti tank omi ile alaja meji jabọ lori ile pẹtẹlẹ to wa ni ẹgbẹ rẹ nipinlẹ Eko.

Iṣẹlẹ naa lo waye ni asalẹ ti awọn eniyan ti n sun ni agbegbe Adeleye, Lady Lark ni agbegbe Bariga nipinlẹ Eko.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ohun to ṣẹlẹ nipẹ tank omi ile alaja meji naa jabọ lori Bungalow to wa ni ẹgbẹ ile alaja naa.

Ori yara meji ni o jale lori ninu ile naa, ti ọmọde kan ati agbalagba si ba iṣẹlẹ naa lọ, ti awọn mẹta miran si farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Ileeṣẹ to n risi ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, NEMA ni wọn ti gbe awọn mẹta to farapa naa lọ si ileewosan.

Bakan naa ni wọn fikun un pe ajọ naa ti ran awọn eniyan lọ si ibẹ lati doola ẹmi awọn eniyan.

Ninu ọrọ tirẹ, Adari ajọ to n risi ọrọ ile nipinlẹ Eko, LABSCA Gbolahan Owodunni Oki ni awọn ti ti ile naa pa, ti wọn si ti paṣẹ fun awọn eniyan lati kuro ninu ile naa.

Wọn ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti ẹni to ba jẹbi iṣẹlẹ naa yoo foju wina ofin.

Ninu ọrọ rẹ, adari Ajọ LABSA naa ni ijiya wa fun ẹni ti ko ba tẹlẹ igbesẹ to rọ mọ ile kikọ nipinlẹ Eko.