E má ṣìwágbọ́, Orí ayélujára ní èsì ìdìbò yóò ti máa jáde ní 2023– INEC

Aworan ajọ INEC

Oríṣun àwòrán, INEC

Ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria (INEC) ti fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe esi idibo lọdun 2023 ni wọn yoo fi ayelujara ṣe agbatẹru rẹ.

INEC ni awọn o tiyin ipinu awọn pada ati pe awọn ti fi opin si fifi ọwọ kọ esi idibo.

Kọmiṣọna ajọ eleto idibo INEC, Festus Okoye lo ṣalaye ọrọ naa nigba to o fesi ọrọ kan to jakiri pe ajọ INEC ti pada si n fi ọwọ kọ esi idibo lọjọ aiku,.

Okoye ni bi eto idibo ṣe waye ni eto idibo gomina ni ipinlẹ Osun ati Ondo nani yoo tẹsiwaju lọdun 2023

Iroyin nani ko dun mọ ọpọlọpọ ọmọ orilẹede Naijiria ninu, ti wọn si tun bọ sita lati pe akiyesi ajọ INEC si iroyin naa.

Ọkan lara awọn to fẹhonuhan loril iroyin naa ni, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubaker, ẹni ti o fi ẹsun kan ajọ naa pe wọn gbero lati ṣe madaru eto idibo lọdun 2023.

Aworan Abubakar Atiku

Oríṣun àwòrán, others

Atiku, ẹni ti o gba ẹnu agbẹnusọ rẹ sọrọ, Daniel Bwala ni ajọ naa ti apejuwe pe wọn ṣe madaru esi ibo lọdun 2023.

Sugbọn Okoye ti wa fi ọkan onikaluku bale pe ajọ INEC ko ni erongba kankan lati fi ọwọ ko esi idibo lọdun 2023 tabi lọjọ iwaju

O ni awọn eeyan kan lo si ajọ naa gbọ, ti wọn si iroyin naa sita fun ọmọ orilẹede Naijiria.

“Ọrọ yii jina si otitọ.”

“A fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe fifi esi idibo si ori ayelujara ti di ohun kan ti yoo wa titi ayeraye.

“Koda fifi esi idibo si ori ayelujara mu isẹ ma rọrun, ti o si fi oto eto idibo han awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ti wọn si le tẹle bi eto idibo ṣe n waye nibikibi.”