Ondo resident doctors strike: Àwọn Dókìtà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní FMC Owo, Ondo

Oríṣun àwòrán, @FMC Owo
Àwọn Dókìtà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní FMC Owo, Ondo
Itọju awọn alaisan lo ti mẹhẹ nile iwosan ijọba apapọ Federal Medical Center nilu Owo latari iyanṣẹlodi awọn dokita to n gbe nile iwosan taa mọ si Resident Doctors lati ọjọ Eti to kọja.
Awọn dokita yi ti wọn pọ niye ju awọn dokita agba lọ nile iwosan naa ni wọn n woṣẹ niran nitori awọn ipenija ti wọn n doju kọ ti wọn ni ijọba ko bikita nipa rẹ.
Ohun ti awọn dokita yi n beere fun ni aaye iṣẹ to yaayi ati gbigba dokita sii bi pupọ ninu wọn ṣe lọ gba iṣẹ loke okun leyi to mu ki iṣẹ pọju fun awọn diẹ to ku.
- Aheregbe festival- Deji Akure kò leè pàṣe láti tí Ọjà Isinkan nítorí kìí ṣe ara Akure
- Eèyàn márùn ún ti wà ní gbaga ọlọ́pàá ṣùgbọ́n ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́- ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù sọ́kọ̀ aya Gomina OyetolaBáwo ni èròjà Fáítámì D ṣe ń dáàbò bo àgọ́ ara wa?
- Ìyàwó wọ sòkòtò fún ayẹyẹ ìgbéyéwò rẹ̀, ní wáhálà bá bẹ́ sílẹ̀
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni pé mo buwọ́lu Tinubu fún ipò Ààrẹ -Obasanjo
- À kò jẹ́ ẹnikẹ́ni lówó oṣù ọdún kàn - Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara
Iyanṣẹlodi yi lo ti mu ki ọpọ mọlẹbi o ko awọn eyan wọn kuro nile iwosan naa ni bi ko ṣe si itọju to peye fun wọn.
Ẹwẹ, awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto ilera to ku bii nọọsi, awọn apoogun (pharmacist), awọn dokita agba (consultants) atawọn oṣiṣẹ ilera to ku ni wọn gbiyanju lati ri pe iṣẹ ko dawọ duro amọ ẹko ko ṣ'oju mimu fun ọpọ ninu awọn alaisan nile iwosan bi ko ṣe si dokita ti yoo maa ṣe ayẹwo to yẹ fun wọn.










