Ṣé lóòtọ́ làwọn èèyàn jó ogúnlọ́gọ̀ ìgbálẹ̀ ni Adamawa láti ṣàtìlẹyìn fún Atiku?

Fidio kan ti n miliẹ titi lori ayelujara bayii, ninu eyii ti ọpọ eeyan ti tan ina lọwọ ti wọn si n kọ orin kan.
Ni kete ti fidio naa jade lọpọ awọ eeyan ti bẹrẹ si n pin fidio ọhun, ti wọn si n fun ni itumọ to wu wọn.
Lati kenya, titi de Naijiria ati DR Congo lawọn eeyan ti n fidio naa fun iroyin ẹlẹjẹ.
Ni Kenya, awọn to n pin fidio na sọ pe awọn to wa ninu rẹ jẹ awọn alatilẹyin Ralia Odinga to n ki fnu aṣeyọri rẹ ninu eto idibo Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ di tan.
Amọ ni Naijiria, awọn to n pin fido naa sọ pe ipinlẹ Adamawa ni wọn ti ya fidio naa.
Ati pe ṣe ni awọn to wa ninu rẹ n jo ogunlọgọ igbalẹ, eyii ti wọn fi n ṣatilẹyin fun Atiku Abubaka lati di Aarẹ Naijiria, ti wọn si n sọ pe awọn ko tẹwọ gba Bola Ahmed Tinubu lati di Aarẹ.
Gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe mọ, ibalẹ ni ami ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣe ipinlẹ Adama ni Najiria ni wọn ti ya fidio naa?
Iwadii ileeṣẹ iroyin BBC fi han pe kii ṣe Naijiria ni fidio naa ti wa.
Ẹka to n ṣe iwadii awọn iroyin ẹlẹjẹ ni BBC sọ pe yatọ si pe kii ṣe Naijiria ni wọn ti ya fidio naa, awọn to wa ni nu rẹ ko tako ẹgbẹ oṣelu APC, wọn ko jo igbalẹ kankan, bẹẹ ni wọn ko ṣe atilẹyin fun Atiku Abubakar.
Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, ọpọ awọn to wa ninu fidio ọhun lo ṣeeṣe ki wọn ma tilẹ mọ Atiku ri, nitori kii ṣe Naijiria ni fidio naa ti wa.
Nibi ni fidio naa ti wa?
Iwadi ileesẹ iroyin BBC fi han pe orilẹ-ede Ghana ni wọn ti ya fidio naa, kii ṣe Naijiria, Kenya tabi DR Congo gẹgẹ bii awọn eeyan kan ṣe n sọ loju opo Twitter.
Ilu Yendi, to wa ni Tishegu, ni Ariwa orilẹ-ede Ghana ni wọn ti ya fidio naa.
Ọjọ kẹjọ, oṣu Kejọ yii si ni wọn ya fidio naa lasiko ti wọn n ṣe ajọyọ kan ti orukẹ rẹ n jẹ “Bugum Chugu Fire Festival.”
Asiko ọdun ina yii lawọn araalu maa n tan ina lọwọ ti wọn a si maa kaakiri igboro.












