Ó kéré tán ènìyàn 20 kú nínú ìkọlù àwọn agbẹ́sùnmọ̀mí sí ilé ìtura

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn eleto aabo lorilẹede Somalia ti ni o kere tan awọn ti doola ẹmi awọn eniyan to le ni ọgọrun nibi ti wọn hamọ si lẹyin ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si ile itura kan ni orilẹede Somalia.

Ileeṣẹ eto ilera lorilẹede Somalia ni o kere tan eniyan mọkanlelogun lo ti ku ninu ikọlu to le ni ọgbọn wakati ti awọn agbesunmọmi al-Shabab fi ṣekọlu si ibẹ.

Awọn agbesunmọmi naa ni wọn lo ado oloro lati fi wọle si ile itura ti wọn pe orukọ rẹ ni Hayat Hotel ni Mogadishu, ki wọn to wa gbakoso ibẹ pẹlu ibọn lakọlakọ.

Araalu ti ko mọ nkankan faragba ninu ikọlu al-Shabab naa

Ninu ọrọ rẹ, Adari ileeṣẹ ọlọpaa, Abdi Hassan ni awọn ti pari eto aabo ni ile itura naa, ti awọn si ti gba isakoso ile itura naa pada.

Wọn ni amọ pẹlu ibanujẹ ọkan ni awọn fi sọ fun awọn araalu pe ọpọlọpọ eniyan ti ko mọ ọwọ mọ ẹṣẹ lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ninu awọn ti wọn doola ẹmi wọn naa, marundinlogun ninu wọn lo wa ni ẹṣẹ kan aye, ẹṣẹ kan ọrun.

Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni pupo ninu ogiri ile itura na lo ti wo palẹ patapata.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn agbesunmọmi naa lo ọkọ meji pẹlu ado oloro lati fi ṣe ikọlu si ile itura naa.

Ile itura naa jẹ ilumọọka ti ọpọlọpọ eniyan ma n lo si to fi mọ awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ma n ṣe ipade nibẹ.

Igba akọkọ kọ ni yii ti ikọ agbẹsunmọmi al-Shabab to jẹ alabaṣiṣẹpọ ikọ al-Qaeda ti n ba ijọba apapọ Somali wọ iya ija.