Kazeem Alli: Àwọn tọ jí alága NURTW Osun gbé ti bèèrè 15 mílíọ̀nù owó ìtúsílẹ̀

Alaga NURTW Osun

Oríṣun àwòrán, @Alli Kazeem

Awon ajinigbe ti kan si idile oga NURTW nipinle Osun, won beere owo itusile milionu meedogun naira.

Eniyan kan to sunmo molebi olori egbe National Union of Road Transport Workers nijoba ibile Isokan ni ipinle Osun, Kazeem Alli, ni ojo Aje ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

O sọ pe awon ajinigbe ti beere owo to jẹ milionu meedogun naira (N15m) fun itusile re.

Kini ọlọpaa sọ nipa iṣẹlẹ naa?

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun ti sọ pe awọn agbebọn kan ni agbegbe Oke Alfa, Apomu ni wọn se ikọlu sí Kazeem Alli pẹlu awọn nkan ìjà olóró bi adà, ti awọn si mu u lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola ninu atẹjade kan tun sọ pe eeyan mẹjọ ni olopaa ti fi panpe òfin mu lori isẹlẹ naa.

Eniyan kan ti ko fe ki iko iroyin BBC News dá orúkọ re so pe awon ajinigbe Alli ti kan si okan lara awon iyawo re, ti won n pe Jemila, ti won si beere owo naa.

Àkọlé fídíò, Udeh Meshack Otobo ni ọmọ Benue to n dín àkàrà tà ní Ofa, Ososgbo, Ilorin àti Ife fi n paw

Bawo ni wọn ṣe ji Alhaji Kazeem Alli gbe?

Eni to ba BBC sọrọ nipa iṣẹlẹ yi sọ pe, Awọn ajinigbe naa ti kan si awọn ẹbi Alli nipasẹ iyawo re Jemila Alli ti Wọn si ti se ikilo fun won lati ma jẹ ki ẹnikẹni mọ nipa idunadura naa.

O tẹsiwaju pe Wọn ti beere fun miliọnu mẹẹẹdogun naira gẹgẹ bi owo itusile ṣugbọn wọn ko jẹ ki won ba Kazeem sọrọ, latigba ti wọn ti ji i gbe.

Ti won si n gbadura fun ipadabọ rẹ l'ayọ ati alaafia.

Gbogbo igbiyanju wa lati ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola soro lori bóyá wọn ti mo sí idunadura to n lọ lọwọ pẹlu awọn mọlebi Alli ni o já sí pabo ni gba ti a n ko iroyin jo.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

Kini ẹgbẹ PDP àti APC n sọ lori iṣẹlẹ yii?

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party ní ìpínlẹ̀ Ọṣun, ti bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ní ìpínlẹ̀ Ọṣun, wọn sí so pe ikọlu Kazeem Alli ni ọwọ ẹgbẹ oṣelu won ninu.

Kola Olabisi to je oludamoran fun eto iroyin fun alaga egbe oselu APC l'Osun, Gboyega Famoodun, ti so saaju pe awon afurasi ti o je janduku ẹgbẹ oṣelu PDP ti pa Alli ti o je okan lara awon oloye egbe naa nijoba ibile Isokan.

Àkọlé fídíò, Mistura Asunmo, Iya 2D:1959 ni mo bẹ̀rẹ̀ eré ṣùgbọ́n ń kò ní ọkọ̀ ẹyọ kan di ìsìnyí

Sugbon nigba to n fesi si oro naa, agbenuso fun egbe oselu PDP nipinle Osun, Oladele Oluwabamiji, ninu atẹjade kan to fi sita nilu Osogbo, ti sọ pé egbe re ko lowo ninu isele ikọlu naa, o si da APC ati Alága ẹgbẹ́ náà Famoodun lebi fun ipenija eto aabo to n koju ipinle Osun.

Àkọlé fídíò, Àṣà àti èdè Yorùbá dùn púpọ̀, o ní ìtumọ̀ kíkún

Ninu atẹjade náà la tun ri ka pe, Ẹgbẹ Oṣelu PDP so fún ẹgbẹ oṣelu APC pe o jẹ itẹwọgba ikuna nla fun ẹgbẹ wọn ti ohun se ijọba lọwọlọwọ lati ma sọkun bi ọmọ alainibaba lori ọrọ aabo eyiti o jẹ ojuṣe akọkọ fun ijọba ti o ba ni ètò to dara nibikibi ni agbaye.