Awakọ̀ bàálú Ethiopia Airlines sáré kọjá 'Bus-Stop' nítorí pé wọ̀n tí sún lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn awakọ meji kan to wa ọkọ baalu Ethiopia ni wọn sare kọja papa ofurufu, ti wọn si kọ lati balẹ si nitori pe wọn ti sun lọ .
Awọn to mojuto irina ọkọ baalu gbinyanju lati pe akeyesi awakọ baalu lẹyin ti wọn kọja apatako ofurufu Ethiopia ni olu ilu Addia Ababa.
Lẹyin ti awọn awakọ baalu naa ji ni wọn to morile ibi ti o ye ki wọn ti balẹ.
Ẹgbẹ Ethiopian Airlines ni awọn ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa.
Nigba ti awọn eeyan n sọrọ lori iṣelẹ naa, ọpọ ni nkan ti o sẹlẹ si ẹnikẹni sugbọn o ya awọn lẹnu pe awọn awakọ naa sun lẹnu isẹ ti wọn si gbagbe pe o ye ki wọn bale ni papa ofurufu
Ọkan lara awọn sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alex Macheras ni; “sisun lẹnu isẹ ni ko jẹ tuntun sugbọn ko wa ma waye lorekore ni koda nitori ẹmi awọn eeyan.
Elomiran bu ẹnu ate lu biu awọn awakọ naa ṣe sun, O ni:
“ Ẹ dẹkun lati ma sun lẹnu isẹ.”
Ethiopian Airlines, Ethiopian Airlines ti wa fi atẹjade sita pe awọn ti fi yoo awọn awakọ baalu naa kuro titi iwadi awọn yoo fi pari.
“Iwaadi ti bẹrẹ lori awakọ baalu naa, ti a si gbesẹ to yẹ lori ọrọ wọn.
"Ẹmi awọn onibara wa jẹ wa lkogun pupọ.”















