Omijé gbojú Anthony Joshua lẹ́yìn tó lulẹ̀ níwájú Oleksandr Usyk lẹ́ẹ̀kejì

Anthony Joshua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Niṣe lomije n bọ loju gbajumọ akanṣẹgbayi ọmọ orilẹede England, Anthony Joshua lẹyin to padanu ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan laarin oun ati Oleksandr Usyk lọjọ Satide mọ Ọjọ Aiku.

Bo tilẹ jẹ pe onka awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan naa lo fun Usyk ni bẹliti igbanu ẹyẹ olubori nilu Jeddah lorilẹede Saudi Arabia, Joshua ṣalaye nigba ti wọn bii lere ọrọ pe, “inu n bimi gidi gan an ni, o dun mi de isalẹ ọkan mi”

Lẹyin to sọ eyi tan, Joshua fọwọ boju rẹ o si mi kanlẹ.

O ni awọn, “ipenija kan ti mo n koju n ni ipa lara mi ṣugbọn n ko ni jẹ ki ijakulẹ ija naa gbe mi ṣubu bi o tilẹ jẹ pe yoo nira diẹ”

Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ẹṣẹ kikan ni idije Olympics lọdun 2012 nilu London. Lẹyin eyi lo bori awọn ija nejilelogun to kọkọ ja gẹgẹ bi akanṣẹjẹun.

Anthony Joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju Usyk ọmọ orilẹede Ukraine.

Kamaru Usman naa lulẹ

Kamaru Usman pẹlu lilẹ ni idije ijakadi igbalode UFC 278.

Kamaru Usman padanu idije ijakadi igbalode UFC 278 ni ipele Welterweight to wa.