Ẹ sọ fún Ademọla Adeleke kó yé sáré kìtìkìtì, sáré kàtàkàtà mọ́, kó gbára dúró gba ìwé ìpẹ̀jọ́ mi – Gómìnà Oyetola

Oríṣun àwòrán, Oteola/Adeleke
Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti fi ẹsun kan gomina ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe o n sa pamọ fun iwe ipẹjọ ti oun fi n tako esi idibo to gbe e wọle gege bii gomina.
Gomina Oyetọla ni gbogbo akitiyan lati fun un ni iwe ipẹjọ lati ile ẹjọ naa lo n ja si pabo pẹlu bi Adeleke ṣe n sare kitikiti, sare katakata lati yẹra fun iwe naa.
Gomina Oyetọla ni ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye nipa eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun ni yoo ba wọn yanju ọrọ naa bayii.
Inu oṣu Keje ni gomina ipinlẹ Ọsun ti yoo pari saa rẹ loṣu kọkanla ọdun 2022, Alaaji Gboyega Oyetọla gba ile ẹjọ ti wọn gbe kalẹ fun gbigbọ awuyewuye gbogbo to suyọ nipa idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ.

Oríṣun àwòrán, Oteola/Adeleke
Ohun ti Oyetọla sọ ninu ipẹjọ rẹ ni pe oun ni ọpọlọpọ idi ati ẹri pe Ademọla Adeleke kọ ni awọn eeyan ilu dibo yan ninu ibo gomina ipinlẹ Ọsun to waye lọjọ kẹrindilogun oṣu Keje.
Agbẹjọro Oyetọla, Amofin agba Kunle Adegoke SAN, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lati igba naa ni wọn ti n wa gbogbo ọna lati fun un ni iwe ipẹjọ yii gẹgẹ bi ilana ofin, ṣugbọn ti gomina tilu didbo yan naa ko fẹẹ gba a.
“Igbẹjọ ti wọn fẹ gbọ kii ṣe igbẹjọ gangan lori awuyewuye to wa nilẹ ṣugbọn a ni awọn iwe ipenija kan lati le jẹ ki olujẹjọ keji tii ṣe Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lati le jẹ ki ile ẹjọ fun wa ni ọna mii lati le jẹ ko gba iwe ipẹjọ nitori pe ko tii gba iwe ipẹjọ lati igba ti a ti gbe ẹjọ wọ ile ẹjọ. O n dibọn. O n yẹra lati ma jẹ ki wọn fun oun. Lati lee baa fi asiko ṣofo.”
Amofin agba Kunle Adegoke ni ohun ti awọn fẹ ṣe bayii ni lati rọ ile ẹjọ naa boya ‘a le fun wa laṣẹ lati le jẹ kii, boya ki wọn lọ lẹẹ mọ iwaju ile rẹ ni o tabi ki wọn fun agbalagba kan ti wọn ba ba ni ile rẹ ni o. Lati le jẹ ki ile ẹjọ gba wi pe a ti fun ni iwe naa”
Ki wa ni ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun sọ si ọrọ yii?
Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun sọ pe lootọ ni awọn yoo joko lọjọ Aje ṣugbọn kii ṣe lati bẹrẹ igbẹjọ lori awuyewuye eto ibo gomina l’Ọṣun laarin gomina Oyetọla ati Ajọ INEC pẹlu Sẹnetọ Adeleke.
Akọwe agba igbimọ igbẹjọ naa David Umar ṣalaye fawọn akọroyin ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria pe ohun ti ijoko ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ọdun 2022 wa fun ni lati gbọ ipẹjọ ipenija ti igun Oyetọla gbe tọ ile ẹjọ naa wa lori ipenija ti wọn n koju lati fun Sẹnetọ Adeleke ni iwe ipẹjọ.
Ohun ti ile ẹjọ naa yoo gbe yẹwo ni boya wọn yoo lo awọn ọna miran lati mu iwe ipẹjọ tọ olujẹjọ naa, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke lara.












