Kò dẹrùn láti ṣe fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ láì sí ìyá mí níbẹ̀ - Ọmọ Iyabo Oko

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ọmọ gbajugbaja oṣere Iyabo Oko, Oduola Olamide ti sọ iriri rẹ gẹgẹ bi oṣere lati igba ti iya rẹ ti dubulẹ aisan.
Olamide to jẹ ọmọ Iyabo Oko, ti babarẹ si jẹ oṣere naa, Tajudeen Akanmu ti wọn n pe ni Koledowo lo ṣe fiimu fun igba akọkọ lai si iya rẹ ni ibẹ pẹlu rẹ.
Ninu ọrọ to kọ si oju opo Instagram rẹ, Oduola Olamide ni bi o tilẹ ṣepe awọn eniyan n sọ fun un pe ko ṣoro lati ṣe fiimu, amọ nitori iya oun to n ṣe aisan, o ṣoro fun un lati ṣiṣẹ de oju ami.
Bakan naa lo kede ki awọn eniyan maa reti fiimu ti oun yoo gbe jade labẹ asia Iyabo Oko Film Production.
‘’Lati ṣe fiimu akọkọ lai si iya mi nibẹ ko dẹrun rara.’’
''Tẹlẹ ti o ma n rọrun fun mi, nitori iya mi wa nibẹ, ni ti o ma n bami fi oju si lati ri pe mọ ṣe aṣeyọri ni gbogbo igba.’’
Amọ bi ko tilẹ si ni gbagede pẹlu mi, adura rẹ ati aduroti rẹ yoo jẹ ki n ṣe aṣeyọri.’’
Bakan naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ, to si ni ki wọn maa rẹti fiimu tuntun ti oun yoo gbe jade pẹlu akọle ‘’THE STORM’’.
Iyabo Oko ni wọn kọkọ kede iku rẹ ni osu kini, ọdun yii ki ọmọ rẹ tun ṣẹṣẹ gbe e jade pe o ji si aye pada lẹyin wakati mẹta ti dokita ti ni o ti jade ni aye.
Oun ni iroyin gbe pe ni asiko ti wọn n wẹ fun un ni ọwọ lati ṣe isinku rẹ, ni o sin jade, to si pada si aye.












