Ṣé lóòtọ́ ni àwọn agbébọn ṣekúpa èèkàn ẹgbẹ̀ òṣèlú APC l’Osun?

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ pe awọn ti n wa eekan ẹgbẹ oṣelu APC kan, Ali Kazeem lẹyin ti awọn afurasi agbebọn kan ji gbe.
Agbẹnuṣọ ileeṣẹ naa, Yemisi Opalola ṣalaye fun BBC Yoruba pe, ọkunrin ọhun, to jẹ alaga ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW, ni Apomu ni awọn ti n wa, awọn ko si le sọ boya o ṣi wa laaye tabi o ti jade laye.
Opalola ni “Logunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, a gbọ awọn eeyan kan gbe alhaji Ali Kazeem ti ọpọ mọ si Kereke Kazuma lọ.”
“Ni kete ti a gbọ naa ni awọn oṣiṣẹ wa lati Ikire bẹrẹ iṣẹ, ti a si ṣawari pe awọn afurasi naa tọpinpin rẹ lati ibudokọ Apomu lọ si Oke Afa, ni Apomu, ki wọn to fi tipatikuku gbe lọ.”
“Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ Toyota Corola dudu kan ti ko ni nọmba ni wọn fi gbe lọ.”
O tẹsiwaju pe awọn akọṣẹmọṣẹ ọtẹmuyẹ ọlọpaa ti bẹrẹ si n wa agbegbe inu igbo ti awọn afurasin naa gbe ọkunrin ọhun wọ lati ṣawari rẹ.
O ni “Ni bayii, ọwọ wa ti tẹ awọn afurasi mẹjọ lori iṣẹlẹ naa.”
“Lọwọ yii, a ko tii le sọ irufẹ ipo ti ọkunrin ọhun wa, boya o ṣi wa laaye ni o tabi o ti jade laye, a ko tii foju ganni rẹ.”
Opalola pari ọrọ rẹ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Olawale Olokode ti fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa balẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa ni ko ni lọ lai foju wina ofin.
Ki ni iroyin to n lọ nigboro?
Ẹwẹ, iroyin to n lọ ni igboro ni pe wọn ti ṣekupa ọkunirn ọhun.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ọkunrin naa wa lara awọn to ṣe ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo gomina to waye loṣu Keje ọdun yii.
Ileeṣẹ iroyin abẹle The Nation jabọ pe lẹyin ti awọn agbebọn naa tọpinpin ọkunrin ọhun de agbegbe Oke Afa ati Timberland ni wọn gbẹmi rẹ ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan an alẹ.












