Akeredolu gbé ipò àwọn Oba kan gá sóké síi gbogbo Ondo ń yọ̀

Awọn ilu ati ileto kaakiri ipinlẹ Ondo lo ti bẹrẹ ajọyọ lati sami awọn ori ade ti wọn gba agbega si ipin miran lati ipin ti wọn wa tẹlẹ.
O kere tan, ọgọrun ọba alaye ni ijọba ipinlẹ Ondo gbega lati gireedi kan si omiran nibi awọn kan ṣe kọja si gireedi A, tawọn miran si bọ si gireedi B.
Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, Bamidele Ademola-Olateju to fi iroyin naa lede lẹyin ipade igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa nilu Akure ṣee lalaye pe ijọba ṣe eleyi lati mu ki idagbasoke o wa sii laarin ilu.

Olateju wipe awọn oloye ati baalẹ to le ni ọgọta ni ijọba tun sọ di ọba alade ki ẹnu wọn o le ka agbegbe ti wọn n dari daadaa.
Kọmiṣọna naa to wipe ijọba ko ni faaye silẹ fun ẹnikẹni lati da omi alaafia ipinlẹ Ondo ru latari igbesẹ yi, fikun pe ẹnikẹni to ba daba iru rẹ yoo foju k'ata ofin.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ni awọn yoo kede gbogbo ọba ti agbega naa de ba laipẹ, diẹ lara awọn ti wọn sọ di ọba gireedi A ni Ọlọ́wá ti Ìgbàrà-Òkè, Ọjọmọ-lúdà ti Ìjẹ̀bú-Ọ̀wọ̀.
Lara won tun ni: Ọwá-Ale ti Ìyọ̀mẹ́ta, Elémùré ti Emùré-Ilé, Alárá ti Ìlárá-Mọ̀kín, Olújàrẹ́ ti Ìjàrẹ́, Olúmòrú ti Imòrú, Ògbólú ti Ìta-Ògbólú, Ọlọ́bà ti Ọ́bá-Ilé, Òdógbó ti Ọ̀mì, Ọrúnjà ti Òdìgbó ati Òkítí ti Ijù.
Ṣaaju ki ijọba to ṣe ikede agbega yi ni awọn ilu ti ọba wọn ri igbega lawọn ijọba ibilẹ mejeejidinlogun to wa ni ipinlẹ naa ti n yọ ayọ oriire naa laarin ilu ati lori ẹrọ ayelujara.













