Aráàlú yarí lórí ọ̀wọ́ngógó, ìyanṣẹ́lódì bẹ̀rẹ̀ kàákirí South Africa

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan lorilẹede South Africa ti kede ọjọ kan lati fi ṣe iyanṣelodi lati fi ẹhọnuhan tako ọwọngogo ounjẹ ati ile gbigbe lorilẹede naa.

Ni olu ilu meji orilẹede naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti dari iyanṣelodi ati ifẹhọnuhan naa, ti wọn si ni awọn fẹ wa gbogbo ọrọ aje orilẹede naa gunlẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Ohun ti wọn n ṣewọde le lori ni aisi iṣẹ fun awọn eniyan ati ọwọngogo ounjẹ nibẹ.

Wọn ni ki ijọba mu adinku ba owo epo bẹntirol, ki wọn fi adinku ba owo ori ati ki wọn fikun un owo oṣu awọn araalu.

Aworan

Oríṣun àwòrán, screengrab

O kere tan, ida mẹta awọn ọmọ orilẹede South-Africa ni ko ni iṣẹ lọwọ ti ajakalẹ aarun Covid-19 si ba wọn finra lọpọlọpọ.

Ni idahun wọn, ijọba ni ẹnikẹni to ba da iṣẹ silẹ ko ni gba owo osu, ti awọn oṣiṣẹ pataki ko si gbọdọ darapọ mọ iyanṣelodi naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni ijọba ko tii ri nkankan nitori awọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.