Owọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí akẹ́kọ̀ọ́ tó fi ọmọ odó pa orogún ìyá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Katsina, sọ pe oun ti mu ọdọkunrin kan ti wọn fura si pe o pa orogún iya rẹ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, SP Gambo Isa, sọ fun BBC pe oogun oloro ni afurasí naa lo, to fi lọ ṣe iṣẹ́ ibi to yọri si iku iya ẹni ọgọ́ta ọdún naa.
Iroyin sọ pe o tun kan baba to bi lọmọ ni apá ati ẹsẹ.
Gẹ́gẹ́ bi ọlọpaa ṣe sọ, akẹkọọ ni ọmọkùnrin naa ni fasiti kan nipinlẹ Katsina, to si jẹwọ pe oun ma n mu oogun oloro.
Iroyin sọ pe ko féràn iyawo baba rẹ rara, to si ma n fi ẹ̀sùn kan pe oun lo fa ipinya laarin baba ati iya òun, botilẹ jẹ awọn mejeeji ti pinya ni ọdun to pẹ.
Bakan naa ni ẹ̀gbọ́n rẹ, to ba iwe iroyin Vanguard sọ̀rọ̀ ni, gbogbo igba ni aburo oun ma n dunkooko pe oun yoo pa obinrin naa.
O salaye pe ọpọ igba ni awọn ti fi ẹjọ́ rẹ sun ni agọ ọlọpaa.
'Ni ọjọ to pa a, niṣe lo fi ọgbọ́n tan baba wa wọ yaara rẹ, to si lọ fi ọmọ odó fọ iyawo baba rẹ lori titi ẹ̀mí fi bọ lara rẹ.
' Eyi waye loju ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin, to wa lati ba iyawo baba wọn ṣeré, àti àwọn ọmọ ọdọ oloogbe meji to wa pẹlu rẹ.
'O tun fi ọmọ odo fọ́ baba rẹ ni egungun ọwọ́ ati ẹsẹ, lasiko to n gbiyanju lati doola ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin naa to tun fẹ́ fi odó lù.'
SP Gambo Isa sọ pe baba naa si n gba itọju nileewosan, ti wọn o si gbe ọmọkunrin naa lọ sílé ẹjọ́ laipẹ.












