''Láti ìgbà tí mo ti gbé ọmọ yìí nínú àtàn ní ayé mi tí yípadà''

Oríṣun àwòrán, Screengrab
Arakunrin Ben-Kingsley Nwashara ti salaye bi oun ṣe di baba ọmọ to he ni oju popo ni ibi ti wọn ju ọmọ naa si.
Nwashara to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo di baba lọsan ganagna lẹyin to ri ọmọbinrin kekere naa ni ẹgbẹ oju ọna ni ipinlẹ Enugu.
Bakan naa lo ni ohun ti fun ni orukọ Testimony
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye re e...

Oríṣun àwòrán, screengrab
Arakunrin naa ni oun ati awọn ọrẹ oun mbọ lati ibi ayẹyẹ ni nkan ni aago mẹsan alẹ ni awọn ri nkan to dabi igi ni oju ọna.
Awọn ọrẹ mi kọkọ ro pe ejo ni ti wọn si fẹ lu igi mọ, amọ mo ni ki a wo finifini ni a ri pe ọmọbinrin ni ti ọmọ naa sun silẹ nibẹ, ko mira amọ oun mi
''Aanu rẹ ṣemi ti mo si gbe lọ si ile lati tọju rẹ''
''Mo kọkọ gbe lọ si ile iwosan fun itọju to peye, ti mo si na ọgọọgọ owo lati ri pe ara rẹ ya pada.''
''Lẹyin naa ni mo gbe lọ silẹ ti mo si ra nkan ọmọ to fi mọ ounjẹ fun.''
''Inu mi dun pe ara rẹ ti bọ si ipo, to si ti n ṣe ere pada.''
Arakunrin naa ni lati igba ti ọmọ naa ti wa ninu aye oun ni gbogbo nkan ti yi
pada fun oun, ti oun si ti di alabukun fun.
Bakan naa lo fikun un pe nitori ati tọju ọmọ naa ṣoro diẹ ni oun fi fi iṣẹ silẹ, amọ ti oun ko kabamọ lori igbesẹ naa.
‘’Awọn eniyan ko naani ẹnikeji mọ, imọtara ẹni lo pọju’’

Arakunrin Kingsley ni alẹ ọjọ ti oun ri ọmọ naa gbe awọn eniyan wa nibẹ, ti ko si ẹni to du ẹmi ọmọ naa.
O tilẹ sọ wi pe awọn ọlọja to wa nibẹ sọ wi pe o ti lẹ ni ọjọ diẹ ti ọmọ naa ti wa ni ibẹ, ti awọn ko si fi ọwọ kan an nitori awọn ko mọ ẹni to ju u sibẹ.
Nitori naa wọn sọ fun un pe, ti o ba wu ki o gbe ọmọ naa abi ko fi sil,ko si eleyill to kan wọn.
O ni nigba ti oun de agọ ọlọpaa ni wọn ni ki oun bu ọwọ lu iwe pe oun a duro ti ọmọ naa.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ afẹsọna rẹ to duro , to si ṣetọju ọmọ naa ni alẹ ọjọ ti o gbe wa.

O parọwa si awọn eniyan lati fẹran ara wọn, ki iwa imọtaraẹni nikan si dopin ni awujọ.
Arakunrin naa ni oun gbe igbeṣẹ naa nitori oun gbagbọ nipa ṣiṣe oorẹ.
Bakan naa lo ni oun yoo sọ itan naa fun ọmọ naa ni ọjọ kan to ba ti dagba, ati pe oun lero lati gbe ọmọ naa kaakiri agbaye, ko jọla bi awọn ọmọ olowo nitori ọmọ naa ti jẹya ṣẹyin.












