Àwọn ọmọ ogún na obìnrin kan, ṣe ènìyàn mẹ́fà mìíràn léṣe nítorí mítà iná

Oríṣun àwòrán, others
Awuyewuye to waye laarin awọn ọmọ ologun ati awọn olugbe agbegbe Nuaso ni Manya Krobo lorilẹede Ghana ti ṣe eyan mẹfa lese.
Ija lo waye lẹyin ti awọn olugbe agbegbe ko lati gba pe ki ajọ to mojuto ọrọ ina lorilẹede naa fi ẹrọ mita sì ile wọn.
Nigba ti awọn ajọ to gba awọn ọmọ fun abo wọn n gbinyanju lati se isẹ wọn ni olugbe agbegbe kọlu wọn ti o si ija.
Ósejumikoro, Citizen Aboaye, to wa ni bẹ salaye pé; "Bí awọn ọmọ ologun ṣe n tẹle awọn osisẹ amunawa bọ, arabinrin kan kọ lati gba mita tuntun naa, ti o si dunkunkun pe oun yoo da epo gbona sori awọn ọmọ ologun.".
"Lẹyin ti wọn din dundu iya fun arábìnrin naa, awọn olugbe agbegbe naa bẹrẹ si ma fi orin bu awọn ọmọ ologun naa."
Gẹgẹ bi Citizen Aboaye ṣe salaye o ni ṣe ni awọn ọmọ ologun naa yín ìbọn soke lati se ẹru bá awọn olugbe agbegbe naa.
Aṣoju agbegbe naa, Samuel Torgbor ti bu enuatelu ikọlu naa pe ko yẹ kí awọn ọmọ ologun ṣe ikọlu si olugbe agbegbe naa.
Ṣugbọn ajọ amonawa ECG tí wa fesi sì lori iṣẹlẹ naa, ti o si di ẹru ẹbi le awọn olugbe agbegbe naa.Madam Sakyiwaa Mensah, agbẹnusọ ECG awọn olugbe agbegbe naa ni wọn jẹbi nítorí wọn gbinyanju lati da epo gbona sori awọn osisẹ amunawa.















